





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè} [Aal Imraan: 7]. O sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ti o ba ti ri awọn ti n tẹle ohun ti o ruju ninu ẹ, àwọn ti Ọlọhun sọ nìyẹn, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niOjiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ – àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè}. Inú rẹ ni Ọlọhun ti sọ pé Oun ni O sọ Kuraani kalẹ fun Anọbi Rẹ, eyi ti o ni àwọn aaya ti itumọ wọn ko ruju, ti a si mọ idajọ wọn, àwọn ni ipilẹ tira naa ati ibuṣẹrisi rẹ, àwọn naa ni ibuṣẹrisi nígbà tí a ba yapa, o tun n bẹ ninu rẹ àwọn aaya miiran ti a le fun ni itumọ oríṣiríṣi, ti itumọ wọn maa n daru lójú àwọn èèyàn kan, tàbí ki o maa lero pe atako n bẹ láàrin rẹ ati aaya mìíràn, lẹyin naa ni Ọlọhun wa ṣàlàyé bi àwọn èèyàn ṣe n lo pẹ̀lú àwọn aaya yii, àwọn ti igbunri kuro nibi òdodo n bẹ ninu ọkan wọn maa fi eyi ti ko ruju silẹ, wọn maa wa gba eyi ti o ruju mu, lati fi le da iruju silẹ ati lati le ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọn a si maa yi itumọ rẹ pada si ohun ti o maa ba ifẹ-inu wọn mu, ṣùgbọ́n àwọn ti ẹsẹ wọn rinlẹ ninu imọ maa mọ eyi ti o ruju yii, wọn maa wa da a pada sibi eyi ti ko ruju, wọn si maa gba a gbọ pe ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni o ti wa, kò si rọrùn ki o daru tabi tako ara wọn, ṣùgbọ́n Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè ti o ni alaafia. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fun iya àwọn mumini, Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ti o ba ti ri awọn ti n tẹle eyi ti o ruju, àwọn yẹn ni Ọlọhun sọ ninu ọ̀rọ̀ Rẹ pe: {Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn}, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn, ki ẹ si ma tẹti si wọn.
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pé: Arákùnrin kan jókòó níwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo ni àwọn ẹrú kan ti wọn maa n pa irọ́ fun mi, wọn tun maa n janba mi, wọn si tun maa n yapa àṣẹ mi, mo maa n bú wọn, mo si maa n lù wọ́n, báwo ni ọ̀rọ̀ mi ati wọn ṣe maa jẹ ni ọdọ Ọlọhun? O sọ pe: “Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, a jẹ pe o ti ṣe déédéé ara wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, ìyẹn maa jẹ alekun fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa gba ẹ̀san alekun naa lara rẹ fun wọn”, o sọ pe: Ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, ni o ba bẹ̀rẹ̀ si nii sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ṣe o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan}, aaya”, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri ohun ti o loore fun emi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di olómìnira.
Tirmiziy ni o gba a waArákùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati wa fi ẹjọ́ bi àwọn ẹrú rẹ ṣe n hùwà sùn, pe wọn maa n pa irọ́ fun un, wọn si maa n janba rẹ nibi agbafipamọ, wọn si maa n rẹ́ ẹ jẹ nibi ibalopọ, wọn si maa n yapa àṣẹ rẹ, oun naa si maa n bu wọn, o si maa n na wọn lati kọ́ wọn ni ẹ̀kọ́, o wa bi i leere nipa bi ọrọ oun ṣe maa jẹ pẹlu wọn ni Ọjọ́ Àjíǹde? Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, tí iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, o maa jẹ alekun ẹsan fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa fi iya jẹ ìwọ naa, wọn si maa gba odiwọn ti o ba le lọ́wọ́ rẹ, wọn si maa fun wọn, ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii n sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Ṣé o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò} [Al-Anbiyaa: 47], wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹni kankan ni Ọjọ́ Àjíǹde, àwọn òṣùwọ̀n si maa wa laarin awọn èèyàn pẹ̀lú déédéé, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri nǹkan kan ti o ni ọla fun èmi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di ọmọlúwàbí nítorí tí Ọlọhun; ni ti ipaya ìṣirò ati ìyà.
Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Dajudaju awọn eeyan kan ninu awọn ẹlẹbọ (awọn ti wọn mu orogun mọ Ọlọhun), ti wọn si pa ọpọlọpọ eeyan, ti wọn tun ti ṣe ọpọlọpọ agbere, ni wọn wa ba Muhammad – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni wọn wa sọ fun un pe: Dajudaju nkan ti o n sọ ti o si n pepe si, nkan ti o daa ni, ti o ba fun wa niroo pe aforijin n bẹ fun nkan ti a ṣe, nigba naa ni o sọkalẹ pe {(Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā}[Al-Furqān: 68], o tun sọkalẹ pe: {Sọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu}[Az-Zumar: 53].
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAwọn ọkunrin kan ninu awọn ẹlẹbọ (awọn ti wọn n mu nkan mii mọ Ọlọhun) wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, wọn si ti pa eeyan lọpọlọpọ ti wọn ti ṣe ọpọlọpọ agbere, ni wọn wa sọ fun Anabi pe: Dajudaju nkan ti o n pepe si ninu Isilaamu ati awọn ẹkọ rẹ nkan ti o daa ni, ṣugbọn bawo ni ọrọ wa o ṣe wa jẹ pẹlu nkan ti a ti ko si ni imu orogun mọ Ọlọhun ati awọn ẹṣẹ nlanla, njẹ ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ wa fun un bi? Nitori naa ni aaya mejeeji yii ba sọkalẹ, nibi ti Ọlọhun ti gba ironupiwada lọwọ awọn eeyan pẹlu pipọ awọn ẹṣẹ wọn ati titobi rẹ, ati pe bi ko ba ṣe titori iyẹn wọn o ba si wa lori ṣiṣe keferi wọn ati àgbéré wọn, wọn ba si ma wọ inu ẹsin yii.
Lati ọdọ ọmọ ‘Umar – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ba awọn eeyan sọrọ ni ọjọ ti wọn ṣi Makkah, ni o wa sọ pe: «Mo pe ẹyin eeyan, dajudaju Ọlọhun ti gbe kuro fun yin igberaga igba aimọkan ati ṣiṣe iyanran wọn pẹlu awọn baba wọn, nitori naa meji ni awọn eeyan: eniire olupaya alapọn-ọnle lọdọ Ọlọhun, ati onibajẹ oloriibu ẹni yẹpẹrẹ lọdọ Ọlọhun, awọn eeyan, ọmọ Anabi Aadam ni wọn, ti Ọlọhun si da Aadam lati ibi erupẹ, Ọlọhun sọ pe: {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán} [Al-Hujrāt: 13]».
Tirmiziy ni o gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ba awọn eeyan sọrọ ni ọjọ ti wọn ṣi Makkah, o wa sọ pe: Mo pe ẹyin eeyan dajudaju Ọlọhun ti gbe kuro fun yin igberaga igba aimọkan ati ijọra-ẹni-loju rẹ, ati fifi awọn baba ẹni ṣe iyanran, ati pe awọn eeyan iran meji ni wọn: Ninu ki o jẹ Mumini eniire olupaya Ọlọhun olutẹle aṣẹ ti n jọ́sìn fun Ọlọhun, eleyii alapọn-ọnle ni lọdọ Ọlọhun, koda ki o ma jẹ ẹni ti o ni ipo ati iran lọdọ awọn eeyan. Tabi ki o jẹ keferi onibajẹ oloriibu, eleyii ẹni yẹpẹrẹ ti ko ni asunsi ni lọdọ Ọlọhun, ti ko si ja mọ nkankan, koda ko jẹ abiyi ti o ni ipo ati ọla. Ati pe gbogbo eeyan pata ọmọ Anabi Aadam ni wọn, ti Ọlọhun si da Aadam lati ibi erupẹ, nitori naa ko lẹtọọ fun ẹni ti ipilẹ rẹ jẹ erupẹ ki o ṣe igberaga ati ijọra-ẹni-loju, ati pe nkan ti o fi idi iyẹn mulẹ ni gbolohun Ọlọhun ti O tobi ti O gbọnngbọn to sọ pe: {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán} [Al-Hujrāt: 13].
Lati ọdọ Az-Zubair ọmọ Al-Awwaam, o sọ pe: Nigba ti (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) sọkalẹ (At-Takathur: 8), Az-Zubair sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ, dajudaju mejeeji ni dudu meji, eso dabinu ati omi? O sọ pe: “Oun naa ni o maa jẹ”.
Tirmiziy ni o gba a waNigba ti ayah sọkalẹ: (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) o n túmọ̀ si pe: Wọn maa pada beere lọwọ wọn nipa idupẹ lori nnkan ti Ọlọhun ṣe ni idẹra le wọn lori ninu awọn idẹra, Az-Zubair ọmọ Al-‘Awwam- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ? Dajudaju idẹra mejeeji ko kii ṣe nnkan ti wọn le bukaata si ibeere ati pe mejeeji ni eso dabinu ati omi! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: Dajudaju wọn maa bi yin leere nipa idẹra pẹlu isẹsi yii ti ẹ wa nibẹ yìí, nitori pe mejeeji jẹ idẹra nla meji ninu awọn idẹra Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe: "Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ".
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ yiyi ibajẹ- oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ kọ kuro nibẹ- pada, ni ibamu bi ikapa ba ṣe mọ, nitori naa ti o ba ri ibajẹ kan, yiyi i pada pẹlu ọwọ jẹ dandan fun un ti ikapa ba n bẹ fun un, ṣugbọn ti o ba kagara kuro nibi ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ pẹlu pe ki o kọ fun ẹni ti o ba ṣe e ki o si ṣàlàyé inira ti o n bẹ nibẹ fun un, ki o si tọ ọ sọ́nà lọ si ibi daadaa dipo aburu yii, Tí o ba kagara kuro nibi ipo yii, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ pẹ̀lú ki o korira ibajẹ yii, yoo si ni ipinnu pe ti oun ba ni ikapa lori yiyi i pada ni ko ba ṣe bẹẹ, Yiyi pada pẹlu ọkan jẹ eyi ti o lẹ julọ ninu awọn ipo igbagbọ nibi yiyi ibajẹ pada.
Lati ọdọ Ibnu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ wọn maa ba wa wí nípa nnkan ti a ṣe ni asiko aimọkan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu, Ati pe dajudaju ẹni ti o ba gba Isilaamu ti Isilaamu rẹ si daa ti o si jẹ olumọkanga olododo; wọn ko nii ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ba ṣe ni asiko aimọkan ninu awọn ẹṣẹ, Ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu pẹ̀lú ki o jẹ ṣọbẹ-ṣelu tabi ki o ṣẹri pada kuro nibi ẹsin rẹ; wọn maa ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ṣe ninu aigbagbọ ati nnkan ti o ṣe ninu Isilaamu.