





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ ki a maa ka Kuraani nígbà gbogbo, ki a si maa tẹra mọ́ kika a ki èèyàn ma baa gbagbe rẹ lẹyin híhá a, o wa tẹnu mọ́ ọn pẹ̀lú ìbúra pe Kuraani yára kuro ninu àyà ju rakunmi ti a so lọ, oun naa ni eyi ti a fi okùn dè ni aarin ẹsẹ, ti eeyan ba n ka a nígbà gbogbo, o maa di i mu, ti o ba si tu u sílẹ̀, o maa lọ.
Lati ọdọ Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”.
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa pe ẹni ti o ni ọlá ju ninu awọn Mùsùlùmí ti o si tun ga ju ni ipo ni ọdọ Ọlọhun ni: Ẹni ti o ba kọ́ Kuraani, ni kika ati hiha, ati kike e ni pẹlẹpẹlẹ, ati agbọye rẹ, ati itumọ rẹ, ti o tun wa kọ́ ẹlòmíràn ni ohun ti n bẹ lọdọ rẹ ninu imọ Kuraani pẹlu lílò ó.
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki a ma maa kirun ni ile, ti yoo fi wa da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ.
Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe dajudaju ẹni tí o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni alẹ, dajudaju Ọlọhun a to o kuro nibi aburu ati nkan ti ko dáa, wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi didide loru (irun oru), wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi awọn iranti yòókù, wọn tun sọ pe: Dajudaju mejeji ni odiwọn ti o kere ju ti o le to ninu kika Kuraani nibi idide oru (irun oru), wọn si tun sọ nkan ti o yatọ si ìyẹn, ati pe o sunmọ pe gbogbo nkan ti wọn sọ yẹn naa ni o daa ti gbolohun yẹn naa si ko o sinu.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ, mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alifu harafi kan ni, lāmu naa harafi kan ni, mīmu naa harafi kan ni».
Tirmiziy ni o gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wípé dajudaju gbogbo Musulumi kọọkan ti o ba n ka harafi kan ninu tira Ọlọhun ni ẹsan kọọkan a máa bẹ fun un, ti wọn yio si ṣe adipele ẹsan naa fun un ni ilọpo mẹwaa iru rẹ. Lẹyin naa ni o wa ṣalaye pẹlu gbolohun rẹ ti o sọ pe: (Mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alif harafi kan ni, lām naa harafi kan ni, mīm naa harafi kan ni): Nítorí naa yio jẹ harafi mẹta ti o ko ẹsan ọgbọn sinu.
Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba.
Al-Bukhari as Mu‘allaq/hanging, with a decisive form‘Āisha iya gbogbo mu’mini – ki Ọlọhun yọnu si i – n sọ pe dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti ojukokoro rẹ pọ gidi gan lori riranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati pe dajudaju o jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba ati aaye ati ìṣesí.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pé: Mo pin irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere o maa jẹ tirẹ, ti ẹru Mi ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi, ti o ba sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), O maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, -O tun maa sọ nígbà miran pe: Ẹru mi fi ọrọ rẹ le Mi lọwọ-, ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), O maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹrú Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem, Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), O maa sọ pe: Eleyii jẹ ti ẹru Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ninu hadiiisi Qudusiy pe: Mo pin Suratul Fatiha lori irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, idaji fun mi, ati idaji fun un. Idaji rẹ akọkọ je: Ọpẹ ati ẹyin ati gbigbe titobi fun Ọlọhun, wọn maa san an ni eyi ti o daa ninu ẹsan lori rẹ. Idaji rẹ keji jẹ: Idirẹbẹẹ ati àdúrà, Mo maa gba a Mo si maa fun un ni nnkan ti o beere. Ti Olukirun ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen) Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun Mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi o si jẹwọ kikari idẹra Mi lori ẹda Mi, ti o ba wa sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, o si jẹ iyi ti o gbòòrò. Ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), Ọlọhun maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹru Mi. Idaji akọkọ ninu awọn ayah yii jẹ ti Ọlọhun, Oun naa ni: (Iyyaaka na’budu) oun ni ijẹwọ pe Ọlọhun ni O ni ẹtọ si ìjọsìn, ati idahun pẹlu ijọsin, ati pe pẹlu rẹ ni idaji ti o jẹ ti Ọlọhun fi wa si opin. Ati pe idaji keji ninu ayah naa, oun ni ti ẹru: (lyyaaka nasta’een) wiwa iranlọwọ lati ọdọ Ọlọhun, ati ṣiṣe adehun Rẹ pẹlu ṣíṣe iranlọwọ. Ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem * Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), Ọlọhun maa sọ pé: Eleyii jẹ idirẹbẹẹ ati adura lati ọdọ ẹru Mi, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, dajudaju Mo ti gba adura rẹ.
Lati ọdọ Saheed ọmọ Al-Musayyab, láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ, o sọ pé: Nigba ti asiko iku Abu Taalib to, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ba a, o si ba Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah ọmọ Mughiirah ni ọdọ rẹ, ni o wa sọ pe: «Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu», ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Ṣe o fẹ gunri kuro nibi ilana Abdul Mutalibi ni, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si yẹ lẹni ti n fi lọ̀ ọ́ pe ki o wi i, ti awọn mejeeji naa si n paara ọrọ naa, titi ti Abu Taalib fi sọ nkan ti o ba wọn sọ gbẹyin pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ti o si kọ lati sọ: Laa illaha illā Allāhu, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mo fi Ọlọhun bura maa maa tọrọ aforijin fun ọ ti wọn o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ», ni Ọlọhun wa sọ ọ kalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ} [Al Taobah: 113]. Ni Ọlọhun tun wa sọ ọ kalẹ nipa Abu Taalib, ti O si sọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́﴿ [Al Qasas: 56].
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wọle tọ ọmọ-iya baba rẹ Abu Taalib ti o n pọka iku lọwọ, ni o wa sọ fun un pe: Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe "laa ilaaha illa Allāhu", gbolohun kan ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu, Ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Irẹ Abu Taalib, ṣe waa fi ilana baba rẹ Abdul Mutalibi silẹ ni? Oun si ni jijọsin fun awọn oriṣa, awọn mejeeji o si yẹ lẹni ti n ba a sọrọ titi ti o fi sọ ọrọ igbẹyin ti o ba wọn sọ pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ilana ẹbọ, ati jijọsin fun awọn oriṣa. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Maa ṣe adua aforijin fun ọ lopin igba ti Oluwa mi o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ, ni gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ba sọkalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n} [Al Taobah: 113], Ni o wa sọkalẹ nipa Abu Taalib gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe: ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà﴿ [Al Qaṣaṣ: 56], Dajudaju oo le fun ẹni ti o ba wu ẹ ni imọna, ati pe nkan ti o jẹ dandan fun ọ ni ki o jiṣẹ, ati pe Ọlọhun ni o máa n fi ẹni ti o ba wu U mọ ọna.
Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: “Àpèjúwe Mumini ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti oorun rẹ daa, ti itọwo rẹ naa si daa, àpèjúwe mumini ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso dabinu, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ si dùn, àpèjúwe munaafiki ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso rayhaanah, ti oorun rẹ dùn, ti itọwo rẹ si korò, àpèjúwe munaafiki ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso hansọla, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ tún korò".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niOjiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ṣe alaye àwọn ìpín awọn eniyan nipa kika Al-Qur’an ati jijẹ anfaani rẹ: Ìpín akọkọ: Mumini ti n ka Kuraani ti o si n ṣe àǹfààní pẹ̀lú rẹ, o da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti itọwo ati oorun rẹ daa, ti awọ rẹ si daa, ti anfaani rẹ si pọ̀, o n lo nnkan ti o n ka, o si n ṣe awọn ẹru Ọlọhun ni anfaani. Ìkejì: Mumini ti kii ka Kuraani, o da gẹgẹ bii èso dabinu, itọwo rẹ dun, ko si ni oorun, ọkàn rẹ ko ìgbàgbọ́ sínú, gẹgẹ bi eso dabinu ṣe ko adun sinu nibi itọwo rẹ ati inú rẹ, ati aihan oorun rẹ ti àwọn èèyàn a gbọ́; torí aihan kika rẹ ti awọn eeyan le fi àyà balẹ si gbigbọ rẹ. Ikẹta: Munaafiki ti n ka Kuraani, o da bii eso rayhaanah, ti oorun rẹ daa ti itọwo rẹ korò, torí igbagbọ ko tun ọkàn rẹ ṣe, ko si lo Kuraani, o wa n ṣe bii mumini loju àwọn èèyàn, oorun rẹ ti o daa jọ kika a, itọwo rẹ ti o korò si jọ iṣe Kèfèrí rẹ. Ikẹrin: Munaafiki ti kii ka Kuraani, o da bii eso hansọla, ko ni oorun, itọwo rẹ si korò, àìní oorun rẹ jọ aika rẹ, ìkorò itọwo rẹ jọ ìkorò ìṣe Kèfèrí rẹ, ko si igbagbọ ninu rẹ, òde rẹ naa o ṣe anfaani, bi ko ṣe pe o tun n ko inira bani ni.