Hedayat “A fruitful harvest”
from the gardens of “ Verses and Hadiths ”
Inspiring Dawah cards that highlight the profound meanings of Quranic verses and Prophetic Hadiths. Presented in an accessible and engaging style to help Muslims gain a deeper understanding of their faith with ease.
About Hedayat
Hedayat is a platform that combines simplicity of design and ease of use
displaying the benefits derived from Verses and Hadiths in
attractive cards with unique designs.
Unique Designs
Cards with unique and attractive designs that express the content of the text
Reliable Materials
Scientifically reliable benefits reviewed by a group of scholars
Easy Browsing
You can browse the cards easily and display them effortlessly
Different Languages
Cards are available in more than 40 languages for the benefit of all
Hadith Cards
Lati ọdọ Abu Huraira, o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba n ṣe anfaani fun obinrin ti ọkọ rẹ ku, ti ko ni ẹni kankan ti o maa moju to awọn alamọri rẹ, ati alaini ti o ni bukaata, ti o si n na owo fun wọn ni ẹni ti o n wa ẹsan lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ẹsan, o da gẹgẹ bii olujagun loju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n ki irun ni oru ti ko ki n rẹ ẹ, ati alaawẹ ti ko ki n túnu.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan, ati pe dajudaju ninu aṣehan ni ki ọmọnìyàn o ṣe iṣẹ kan ni oru, lẹyin naa ki o wa ji ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ, ki o wa sọ pe: Irẹ lagbaja, mo ṣe nkan bayii bayii ni alẹ ana, ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ ni alẹ, yio waa ji lati ṣi gaga aṣiri bibo Ọlọhun kuro».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Musulumi ẹlẹṣẹ ni o ṣeeṣe ki o ri amojukuro Ọlọhun ati aforijin Rẹ, ayaafi ẹni ti o ba n fi ẹṣẹ han ní ti ṣiṣe faari ati jijẹ aṣa, oun o lẹtọọ si amojukuro; latari pe yio da ẹṣẹ ni oru, lẹyin naa yio ji ni ẹni ti Ọlọhun ti bo aṣiri rẹ, ni yio ba sọ fun ẹlòmíràn pe oun da ẹṣẹ bayii ni ana, ti o si sun ti Oluwa rẹ ti bo o ni aṣiri, ni yio ba ji ti yoo waa tu aṣiri bibo Ọlọhun lori rẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra- ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-: «Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba sọ lẹyin ti o ba pari awọn irun ọranyan: Ni igba mẹtalelọgbọn pe: “Subhaanollooh”, oun naa ni mimọ Ọlọhun kuro nibi àléébù. Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "AlhamduliLlāhi" oun naa ni yiyin In pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu inifẹẹ Rẹ ati gbigbe E tobi. Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "Allāhu akbar” oun ni pe Ọlọhun ni O tobi ju Oun si ni O gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ. ki o mu onka naa pe ọgọ́rùn-ún pẹlu gbolohun: "Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa ala kulli shayhin qadeer" itumọ rẹ si ni pe: Ko si ẹni ti ijọsin tọ si pẹ̀lú ẹtọ ayaafi Ọlọhun ni Oun nikan ṣoṣo ko si orogun fun Un, ati pe Oun- mimọ n bẹ fun Un- nìkan ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si lẹtọọ si ẹyin pẹlu ifẹ ati igbetobi yatọ si ẹlòmíràn tí ó yatọ si I, ati pe Oun ni Olukapa ti nkankan o si le da A ni agara. Ẹni ti o ba wa sọ ìyẹn wọn yio pa aṣiṣe rẹ rẹ wọn o si ṣe aforijin rẹ, koda ki o pọ bi foomu funfun ti maa n leke omi okun nígbà tí o ba n ru soke.
Lati ọdọ Tamiim Ad-Daariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹsin ìmọ̀ràn ni”, a sọ pé: Fún tani? O sọ pe: “Fún Ọlọhun, ati fun tira Rẹ̀, ati fun ojiṣẹ Rẹ, ati fun awọn aṣiwaju Mùsùlùmí ati apapọ wọn”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹsin duro lori imọkanga ati ododo, titi ti eeyan fi maa pé e gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun ṣe ṣe e ni dandan, ni pípé láìsí ikudiẹ-kaato nibẹ tabi irẹjẹ. Wọn wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Ìmọ̀ràn fun tani? O sọ pe: Akọkọ: Ìmọ̀ràn fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: Pẹ̀lú mimọ iṣẹ kangá fun Un, ati ki èèyàn ma da orogun pọ̀ mọ́ Ọn, ki a si gbagbọ ninu ijẹ Oluwa Rẹ, ati ìní-ẹ̀tọ́ si ìjọsìn Rẹ, ati awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ, ati gbigbe ọ̀rọ̀ Rẹ tobi, ati ipepe lọ sibi ìní ìgbàgbọ́ si I. Ìkejì: Ìmọ̀ràn fun tira Rẹ tii ṣe Kuraani Alapọn-ọnle: Pẹlu pe ki a ni adisọkan pe ọrọ Rẹ ni, oun si ni tira Rẹ ti o kẹyin, o si ti pa gbogbo àwọn ofin ti o ṣíwájú rẹ̀ rẹ́, a maa gbe e tobi, a si maa ka a bi o ṣe tọ́. A maa lo eyi ti ko ba rújú nínú ẹ, a si maa yọnu si èyí ti o ba rújú ninu ẹ, a si maa le àwọn èèyàn kuro nibi itukutuu àwọn ti n yi itumọ rẹ padà, a si maa woye si awọn wàásù rẹ, a si maa tan imọ rẹ ka, a si maa pepe si i. Ìkẹta: Ìmọ̀ràn fun ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Pẹ̀lú ki a ni adisọkan pe oun ni igbẹyin àwọn ojiṣẹ, ki a si gba a lododo nibi nǹkan ti o mu wa, ki a si tẹle àṣẹ rẹ, ki a si jinna si ohun ti o bá kọ̀. Ki a si ma jọ́sìn fun Ọlọhun àyàfi pẹ̀lú nǹkan ti o mu wa, ki a si maa gbe iwọ̀ rẹ tobi, ki a si maa pọn ọn le, ki a si maa tan ipepe rẹ ká, ki a si maa fọn ofin rẹ ka, ki a si maa tako àwọn ẹ̀sùn ti wọn ba fi kan an. Ikẹrin: Ìmọ̀ràn fun awọn aṣiwaju àwọn mùsùlùmí: Pẹ̀lú riran wọn lọ́wọ́ lórí òdodo, ki eeyan ma si du àlámọ̀rí naa mọ́ wọn lọ́wọ́, ki èèyàn si maa tẹti ki èèyàn si maa tẹle àṣẹ wọn nibi itẹle ti Ọlọhun. Ikarun-un: Ìmọ̀ràn fun awọn Mùsùlùmí: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn ati pípè wọn, ati ki èèyàn má fi suta kan wọn, ati inifẹẹ oore fun wọn, ati kikun wọn lọ́wọ́ lori dáadáa ati ìpayà.
Lati ọdọ Sahl ọmọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ọjọ́ Khaibar pé: Dajudaju maa fun arakunrin kan ni asia yii ni ọla ti Ọlọhun maa ti ipasẹ rẹ fun wa ni iṣẹgun, o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa nífẹ̀ẹ́ rẹ”, o sọ pe: Àwọn ènìyàn sùn ní alẹ́ náà tí wọ́n ń jiroro laarin ara wọn tani wọn yoo fun.” Nígbà ti ilẹ̀ mọ́, àwọn èèyàn lọ ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ọkọọkan ninu wọn si n fẹ ki wọn fun oun, o sọ pe: “Ibo ni ‘Ali ọmọ Abu Talib wà”? Wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ojú n dùn ún. O sọ pe: “Ẹ ranṣẹ si i”, wọn si mu u wa ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa tutọ́ si oju rẹ mejeeji, o si ṣe adura fun un, o si gbadun gẹgẹ bii pe inira kan kan ko mu u, o wa fun un ni asia náà. Ali wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki n maa ba wọn ja titi wọn fi maa da bii wa? O sọ pe: “Maa lọ ni pẹlẹpẹlẹ titi waa fi dé agbegbe wọn, lẹyin naa pe wọn sinu Isilaamu, sọ nnkan ti o jẹ dandan le wọn lori ninu ẹtọ Ọlọhun fun wọn nibẹ. Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun awọn saabe nípa ìṣẹ́gun awọn mùsùlùmí lori awọn Juu Khaibar ni ọjọ keji, ìyẹn maa waye lati ọwọ arakunrin kan ti oun maa fun un ni asia, oun naa ni àsíá tí àwọn ọmọ ogun maa n fi ṣe àmì wọn, Ati pe arakunrin yii ninu awọn iroyin rẹ ni pe o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa si nífẹ̀ẹ́ rẹ, Àwọn saabe si sùn ni alẹ ti wọn n jíròrò ti wọn si n sọ̀rọ̀ nipa pe tani wọn maa fun ni asia naa? Ni ti ìfẹ́ si iyì ńlá yii, Nigba ti o di àárọ̀ wọn lọ sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, gbogbo wọn ni wọ́n n nírètí pé àwọn á gba iyì yìí, Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa beere nipa 'Ali ọmọ Abu Talib- ki Ọlọhun yọnu si i-? Wọn sọ pé: O rẹ ẹ, ojú rẹ mejeeji n dun un. Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ranṣẹ si i, wọn si de pẹlu rẹ, o wa tu itọ si oju 'Ali mejeeji ninu itọ rẹ abiyi, o ṣe adura fun un, o si gbádùn nibi aisan rẹ, o wa da gẹgẹ bii pe inira kan ko mu u tẹ́lẹ̀, o wa fun un ni asia naa, o pa a láṣẹ pẹlu pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ titi o fi maa sunmọ aaye ààbò awọn ọta ti o si maa fi gbigba Isilaamu lọ wọn, ti wọn ba da a lohun; o maa sọ fun wọn nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn ọran-anyan. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé fun 'Ali nipa ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ si oju ọna Ọlọhun ati pe ti ipepe ba jẹ okunfa ìtọ́sọ́nà arakunrin kan ṣoṣo ìyẹn loore fun un ju ki rakunmi pupa jẹ tirẹ̀ lọ, eyi ti o ṣe pe oun ni o níye lórí julọ ninu awọn dukia larubawa, yio ni i tabi ki o fi ta ọrẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mumini o gbọdọ maa korira muminah, ti o ba korira iwa kan lara rẹ, yio yọnu si omiran lara rẹ» tabi o sọ pe: «Yatọ si i».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ fun ọkọ ki o maa korira iyawo rẹ ni ikorira ti yio ti i debi ki o maa ṣe abosi rẹ ati ki o pa a ti ati ki o ma ya si i; nitori pe dajudaju ọmọniyan wọn da a mọ aipe ni, ti o ba wa korira iwa buruku kan ni ara rẹ, yio ri iwa miran ti o daa; nitori naa yio yọnu si èyí tí o daa ti o ṣe deede, ki o si ṣe suuru lori èyí tí ko daa ti ko yọnu si, èyí tí yio mu un ṣe suuru ti ko si nii korira rẹ ni ikorira ti yio gbe e lọ s'ibi kikọ ọ.
Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun bá wa yọnu si i, o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - sọ bayi pe: "È sun mọnra, ẹ se daada, ki ẹ lọ mọ pe kò sí ẹnikan ninu yin ti yoo la pọlu iṣẹ ọwọ rẹ" awọn ọmọlẹyìn rẹ sọ bayii pe: Se ati iwọ naa irẹ ojisẹ Ọlọhun? Anọbi daun oni: ati emi naa, ayaafi ki Ọlọhun da gaga ikẹ Rẹ ati aanu Rẹ lemi lori (ki Ọlọhun siji àánu Rẹ bò mi) .
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ṣe awọn ọmọlẹyìn loju kòkòrò (o fa ifẹ wọn) síbi imaa sisẹ, ati ki wọn si bẹrù Ọlọhun bi wọn ba se ni agbara mọ, láì ṣe àṣe kọja ààlà, ati láì ṣe asee to, ki wọn ni eero iṣẹ àṣe dara pẹlu imáa ṣe iṣẹ wọn nítorí ti Ọlọhun (aniyan tori Ọlọhun) ati imáa tẹlé ilana ati alaalẹ anọbi, ki iṣẹ wọn le jẹ àtéwọgbà, atipe ki o jẹ okunfa isọkalẹ àánu Ọlọhun fún wọn. O si tun fún wọn niro pe isẹ enikọọkan yin nikan ko lee gbayinla, sugbọn afi ki ẹ rí ikẹ gba lọdọ Ọlọhun. Wọn sọ pe: titi o fi de orí rẹ, irẹ ojisẹ Ọlọhun, iṣẹ rẹ ko lee gbaọla toun ti bi o se tobi to? Anọbi sọ pe: titi ofi dé orí mi, ayaafi ki Ọlọhun bomi lasiri pẹlu aanu Rẹ.
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o sọ pe: Dajudaju Ummu Habeebah ọmọ Jahsh ti o wa labẹ 'Abdur Rahman ọmọ 'Aof, o gbe ẹjọ́ ẹjẹ lọ sọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ fun un pé: "Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ". O si jẹ ẹni ti maa n wẹ nibi gbogbo irun.
Muslim gba a waẸnikan ninu awọn saabe lobinrin fi ẹjọ àìdá ẹjẹ rẹ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa pa a láṣẹ kí ó má kirun ni odiwọn igba ti ẹjẹ nnkan oṣu rẹ fi maa n dè é mọle ṣíwájú ki àlámọ̀rí pajawiri yii o to ṣẹlẹ̀ si i, lẹyin naa o maa wẹ, o si maa kirun, o si jẹ ẹni ti maa n fínnú-fíndọ̀ wẹ fun gbogbo irun kọọkan.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wa ni khutubal haajah: Innal hamda lillah, nasta’eenuhu wa nastagfiruhu, wa na’uudhu bihi min shuruuri anfusinaa, man yahdii llohu falaa mudilla lahu, wa man yudlil fa laa haadiya lahu, wa ash-hadu an laa ilaaha illallohu, wa ash-hadu anna Muhammadan ‘abduhu wa rosuuluhu, (Yaaa ayyuhan naasut taqoo Rabbakumul lazee khalaqakum min nafsinw waahidatinw wa khalaqa minhaa zawjahaa wa bas sa minhumaa rijaalan kaseeranw wa nisaaa’aa; wattaqul laahallazee tasaaa ‘aloona bihee wal arhaam; innal laaha kaana ‘alaikum Raqeeba) (An-Nisa: 1), (Yaaa ayyuhal lazeena aamanut taqul laaha haqqa tuqaatihee wa laa tamootunna illaa wa antum muslimoon) (Aal-Imran: 102), (Yaaa ayyuhal lazeena aamanut taqul laaha wa qooloo qawlan sadeedaa(70) Yuslih lakum a’maalakum wa yaghfir lakum zunoobakum; wa mai yuti’il laaha wa Rasoolahoo faqad faaza fawzan ‘azeemaa) (Al-Ahzab: 70-71).
رواه أبو داود والترمذي والنسائي وابن ماجه وأحمدỌmọ Mas’ud - ki Ọlọhun yọnu si i - n sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wọn ni khutubal haajah, oun ni wọn maa n sọ nibi ìbẹ̀rẹ̀ ọrọ nibi khutubah ati níwájú bukaata wọn, gẹgẹ bii khutubah igbeyawo ati khutubah irun Jimoh ati eyi ti o yatọ si wọn, Ati pe khutubah yii ko awọn ìtumọ̀ ti o tobi sinu bii alaye pe Ọlọhun lẹtọọ si gbogbo awọn iran ọpẹ, ati wiwa iranlọwọ lọdọ Rẹ ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati bibo awọn ẹṣẹ ati mimu oju kuro nibẹ, ati sisadi I kuro nibi gbogbo aburu, ati awọn aburu ẹmi ati eyi ti o yatọ si wọn. Lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju imọna ọwọ Ọlọhun ni o wa, ẹni ti O ba fi mọna ko si oluṣini-lọna kan fun un, ẹni ti O ba ṣi lọna ko si atọnisọna kan fun un. Lẹyin naa o darukọ ijẹrii imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo pe oun ni pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, ati pe ijẹrii iṣẹ́-rírán ni pe dajudaju Muhammad jẹ ẹrusin Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ. O pari khutubah yii pẹlu awọn aayah mẹta ti wọn ko àṣẹ pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sinu pẹlu ṣiṣe awọn àṣẹ Rẹ ati jijina si awọn nǹkan ti Ó kọ̀ lati fi wa oju rere Ọlọhun, ati pe dajudaju ẹsan ẹni ti o ba ṣe iyẹn ni dídára awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ati pipa awọn aburu rẹ ati aforijin awọn ẹṣẹ ati iṣẹmi ti o mọ ni aye ati erenjẹ pẹlu alujanna ni ọjọ igbedide.
Lati ọdọ Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo ṣafẹku ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) lori ibusun loru ọjọ kan, mo wa nfi ọwọ wa a kiri bẹẹni ọwọ mi kan inu atẹlẹsẹ rẹ nigbati o wa ni iforikanlẹ, ti o gbe gigisẹ rẹ mejeeji sí oke, ti nsọ bayi ninu adura rẹ pe: "irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ.
Muslim gba a waAishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: mo sun lẹgbẹ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), mo ṣe afẹku rẹ ni oru (mi o ri), mo wa fi ọwọ mi woo ni ààyè ti o ma ti nkirun ninu yàrá, bayi ni mo kan lojiji pe o nkirun lọwọ ti gigisẹ rẹ mejeeji si wa ni iduro, bẹẹ sì ni o nsọ bayi pe: (mo nwa isọ) mo nṣe atẹgun sọdọ Rẹ (pẹlu ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ) sí mi tabi sí awọn ijọ mi, (ati) pe mo nwa isọra (pẹlu amojukuro Rẹ) ati amojukuro re ti o pọ (kuro nibi ijẹniya Rẹ), (mo wa idaabobo lọdọ Rẹ pẹlu araarẹ) ati pẹlu awọn iroyin rirẹwa Rẹ lọdọ awọn iroyin titobi Rẹ, nigbati o jasipe ẹnikan ò lee ṣọ ni lọdọ Rẹ àyaàfi ìwọ fún rara Rẹ, kò sibi aa salọ fún akoyọ, bẹẹ sì ni kò sibi ti a le sadi lati sa fún Ọlọhun ayaafi ki a sadi Ọlọhun, (Mi o le ṣe onka ẹyin fún irẹ Ọlọhun), mi o nikapa, mi o sì lè dé òpin ati onka lati ka gbogbo idẹra Rẹ tan nitori ikagara mi, bẹẹ ni mi o le ka daada Rẹ tan gẹgẹbi O ṣe lẹtọ si i, koda bi mo ba ṣe igbiyanju ati akitiyan láti ṣe bẹẹ, (gẹgẹ bí Irẹ Ọlọhun ṣe ṣe ẹyìn fún ara Rẹ) Iwọ ni O ṣe ẹyìn fún Pàápàá ara Rẹ, ẹyin ti o ba ọ mu, taani ẹni náà tí o ni ikapa lati mu ẹyin Rẹ wá ní bo ṣe yẹ?!