





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ, ìyẹn ni igba ti: (ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà)) Al-An’am, Ayah 158. Alukiyaamọ maa tó, ti ọkùnrin meji si ti tẹ aṣọ silẹ láàrin ara wọn, wọn ko si nii lee ta ọjà fun ara wọn bẹẹ ni wo ko si nii lee ka a padà, alukiyaamọ maa tó, ti èèyàn si ti bu wàrà ràkúnmí rẹ lọ ti ko si nii le mu u, alukiyaamọ maa tó, ti ó sì ti tún àmù omi rẹ ṣe, ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ mu nínú ẹ, alukiyaamọ maa tó, ti ẹnìkan nínú yin si ti gbe oúnjẹ rẹ sí ẹnu, ko si nii lee jẹ ẹ”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niOjiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ti o tobi julọ ni ki oòrùn yọ lati ibuwọ rẹ dipo ki o yọ lati ibuyọ, ati pe igba ti awọn eniyan ba ri i, wọn maa gbagbọ lapapọ, Nigba yẹn igbagbọ alaigbagbọ ko nii ṣe e ni anfaani, iṣẹ rere tabi ironupiwada ko nii ṣe anfaani. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọjọ igbende maa de lojiji; o maa tó ti awọn eniyan sì maa wa lori awọn iṣesi wọn ati lori awọn eto igbesi aye wọn; Ọjọ igbende maa de ti olutaja ati oluraja ti maa tẹ aṣọ wọn laaarin wọn ti wọn ko si nii le ta a fun ara wọn ti wọn ko si tun nii le ka a, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si ti bu wara rakunmi rẹ ti o ni wàrà tó pọ̀, ko si nii mu u, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si n tun àmù omi rẹ ṣe ti o si tun n fi amọ rẹ́ ẹ, ti ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ ni omi mu nínú ẹ, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si ti maa gbe okele rẹ de ẹnu rẹ lati jẹ ẹ ti ko si nii jẹ ẹ.
Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára, olupepe kan maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, wọn maa garùn wọn si maa wò, yoo wa sọ pé: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, lẹyin naa o maa pe pe: Ẹyin ọmọ iná, wọ́n maa garùn wọ́n sì maa wò, o maa waa sọ pe: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, wọn maa du u, lẹyin naa o maa sọ pé: Ẹyin ọmọ alujanna, gbére, ko si ikú mọ, ẹyin ọmọ iná, gbére, ko si ikú mọ, lẹyin naa ni o ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná} [Maryam: 39], àwọn wọ̀nyí wa ninu igbagbera ni àwọn ará ayé, {wọn kò sì gbàgbọ́} [Maryam: 30]”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, ṣalaye pe wọn yoo mu iku wa ni ọjọ Ajinde, gẹgẹ bii irisi akọ agutan ti o ni funfun ati dudu ninu rẹ, Wọn maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna! Wọn maa garun, wọn maa gbe ori wọn sókè, wọ́n si maa wò, Ó maa sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ mọ èyí? Wọ́n maa sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, ikú nìyí, gbogbo wọn sì ti rí i, wọ́n sì mọ̀ ọ́n. Lẹ́yìn náà ni olupepe naa maa pe pe: Ẹyin ọmọ ina, wọn maa ga ọrùn wọn, wọn maa gbe ori wọn sókè, wọ́n sì máa wò, Ó maa sọ pé: “Ṣé ẹ mọ èyí? Wọ́n maa sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, ikú nìyí, gbogbo wọn sì ti rí i, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; Wọn maa du u, lẹyin naa ni olupepe naa maa sọ pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, ẹ maa wa nibẹ gbere, ko si ikú, ẹyin ọmọ ina, ẹ máa wà nibẹ gbere, ko si ikú. Ki ìyẹn le jẹ alekun idẹra àwọn mumini, ati ìjìyà fun awọn Kèfèrí. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́}. Ni ọjọ igbedide, wọn maa ya àwọn ọmọ alujanna ati awọn ọmọ ina si ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn si maa wọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ ba kangun si ti yoo si ṣe gbere nibẹ, Alaburu maa ká abamọ; torí pé ko ṣe dáadáa, ati ẹni tí ó ṣe to kù díẹ̀ kaato; torí ko lékún nibi iṣẹ rere.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Awọn Juu ati Kristẹni maa n ka Taoreeta pẹ̀lú èdè Hébérù, wọn si maa n túmọ̀ rẹ pẹlu èdè Lárúbáwá fun awọn Mùsùlùmí, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ẹ má gba ọ̀rọ̀ àwọn Júù àti Kristẹni ni ododo, ẹ si ma pe e ni irọ, ki ẹ sọ pé: {A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa} [Al-Baqarah: 136] Aayah”.
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kilọ fun awọn ìjọ rẹ láti ṣọ́ra fun gbigba ẹtan pẹ̀lú nǹkan ti àwọn Júù àti Kristẹni n gbà wá nínú àwọn ìwé wọn, Níbi tí àwọn Júù ìgbà ayé Ànábì máa ń ka Taoreeta ní èdè Hébérù. Ó jẹ́ èdè àwọn Júù, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ ní èdè Lárúbáwá, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ẹ ma gba ọrọ àwọn Júù àti Kristẹni ni ododo, ẹ si ma pe e ni irọ, èyí níbi ohun ti a ko mọ ododo rẹ yatọ si irọ rẹ; Torí pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pa wa láṣẹ ki a ni igbagbọ ninu Kuraani ati Ìwé ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun wọn, ṣùgbọ́n ko si bi a ṣe fẹ mọ èyí tí ó ni àlàáfíà ninu ohun ti wọn n sọ nipa awọn Ìwé sánmọ̀ yẹn yatọ si èyí tí kò ni àlàáfíà; tori ko wa ninu ṣẹria wa ohun ti o maa ṣàlàyé ododo rẹ yatọ si irọ rẹ, Nítorí náà a maa kóra ro, a ko nii gba ọrọ wọn ni ododo; ki a ma baa kópa pẹ̀lú wọn nibi ohun ti wọn yi padà ninu ẹ, a ko si nii pe ọrọ wọn ni irọ; bóyá o le jẹ òdodo, ki a ma baa lọ tako ohun ti wọn pa wa láṣẹ ki a gbagbọ, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa pa wa láṣẹ ki a sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.” [Al-Baqarah: 136].
Lati ọdọ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ.
Abu Daud ni o gba a waIbnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- n ṣàlàyé pe àwọn suura Kuraani Alapọn-ọnle maa n sọ̀kalẹ̀ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko si nii mọ ibi ti asopọ rẹ ti ge ati òpin rẹ, titi ti “BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM” fi maa sọ̀kalẹ̀ fun un, igba naa ni o to maa mọ pe suura ti o ṣáájú ti parí, oun si ni ibẹrẹ suura tuntun.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”.
Abu Daud ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé wọn maa sọ fun ẹni ti n ka Kuraani, ti n lo ohun ti o wa ninu rẹ, ti n dunni mọ́ ọn ni kíkà ati híhá, ti o ba ti wọ alujanna- pé: Maa ka Kuraani, ki o si maa gòkè pẹ̀lú ìyẹn nibi awọn ipò alujanna, ki o si maa ke e gẹ́gẹ́ bí o ṣe maa n ke e ni aye pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ati ifarabalẹ; tori pe ibùgbé rẹ n bẹ nibi opin aaya ti o maa kà.
Lati ọdọ Abu Abdir-Rahmaan As-Sulamiy- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Awọn ti wọn maa n kọ́ wa bi a ṣe maa ka Kuraani ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wa pe àwọn maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ ti o wa ninu ẹ, wọn sọ pé: A wa kọ́ imọ ati iṣẹ.
Ahmad ni o gba a waAwọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu Kuraani, wọn ko si nii bọ si ibòmíràn titi ti wọn fi maa kọ́ imọ ti o wa ninu awọn aaya mẹ́wàá yii ti wọn si maa lò ó, o maa waa ja si pe wọn kọ imọ ati iṣẹ papọ nìyẹn.
Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi Ubay ọmọ Kahb léèrè nipa aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun, o wa ṣe iyèméjì nibi dáhùn, lẹ́yìn náà ni o wa sọ pé: Oun ni aayatul Kursiyy: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá}, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe atilẹyin fun un, Anọbi wa lu u ni àyà lati tọka si pe o kún fun imọ ati ọgbọ́n, o wa ṣe adua fun un pe ki o maa dunnu pẹ̀lú imọ yii ki o si rọrùn fún un.
Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹyin naa o maa fi méjèèjì pa ibi ti o ba ṣeé pa ni ara rẹ, o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ ati oju rẹ, ati ẹ̀yà ti iwájú ninu ara rẹ, o maa ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹẹmẹta.
Bukhaariy gba a waNínú ìtọ́sọ́nà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni pe o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, o si maa gbe wọn sókè- gẹgẹ bi ẹni tí n ṣe adua- o maa wa rọra fẹnu fẹ́ atẹ́gùn si i pẹ̀lú itọ́ díẹ̀, o maa ka àwọn suura mẹtẹẹta naa: {Qul Uwal Loohu Ahad} ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq} ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹ́yìn náà ni o maa fi atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pa ibi ti o ba ṣee pa ni ara rẹ; o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ, ati ojú rẹ, ati ẹya iwaju ara rẹ, o maa pààrà rẹ ni ẹẹmẹta.
Lati ọdọ 'Adiyyu ọmọ Haatim, lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu".
Tirmiziy ni o gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju awọn Juu ni ìjọ kan ti Ọlọhun binu si wọn, nitori pe wọn mọ ododo wọn ko si ṣiṣẹ pẹlu rẹ. Ati pe awọn Nasara ni ìjọ ẹni anu; nitori pe wọn ṣe iṣẹ laini imọ.