





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii wo àwòrán ẹrú ati ara wọn, boya o rẹwà ni abi o burẹ́wà? Boya o tobi ni abi o kéré? Bóyá o ni alaafia ni abi o n ṣe àìsàn? Ko si nii wo dúkìá wọn, bóyá o pọ ni abi o kéré? Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii fi àwọn nǹkan wọ̀nyí bi àwọn ẹrú Rẹ, ko si nii ṣe ìṣirò wọn lórí rẹ ati bi wọn ṣe yatọ si ara wọn nínú ẹ, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn wọn ati nǹkan ti o wa ninu ẹ bii ipaya ati àmọ̀dájú, ati ododo ati imọkanga, tabi gbigbero ṣekarimi ati ṣekagbọmi, O si tun maa wo iṣẹ wọn bóyá o dára ni abi ko dára, O maa wa sẹsan lori ẹ.
Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Láàrin ìgbà tí a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, ni arákùnrin kan ba yọ si wa, ti aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dúdú gan, a ko ri oripa ìrìn-àjò ni ara rẹ, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jókòó si ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o si fi eékún rẹ méjèèjì tì sí ara eékún rẹ méjèèjì, o wa gbe ọwọ́ rẹ méjèèjì lori itan rẹ, o wa sọ pé: Irẹ Muhammad, sọ fún mi nipa Islam, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ”, o sọ pé: Òdodo ni o sọ, o sọ pé: Ẹnu yà wá fun un, o n bi i leere, o si tun n sọ pé òdodo ni o sọ, o sọ pé: Sọ fun mi nipa igbagbọ, o sọ pé: “Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ̀, ati awọn ìwé Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o si ni igbagbọ ninu kádàrá, oore rẹ ni ati aburu rẹ”, o sọ pe: Òdodo ni o sọ, o sọ pe: Sọ fun mi nipa ṣíṣe dáadáa, o sọ pe: “Ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ìwọ ko ba ri I, Òun n ri ọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa àsìkò ti aye maa parẹ, o sọ pe: “Ẹni ti wọn n beere nipa nǹkan lọ́wọ́ rẹ ko ni imọ nipa nǹkan naa ju ẹni tí n beere lọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa awọn àmì rẹ, o sọ pe: “Ki ẹrú lóbìnrin bi olówó rẹ, ati ki o ri awọn ti ko wọ bàtà ti wọn wa ni ihoho ti wọn jẹ tálákà tí wọn n da ẹran jẹ, ti wọn yoo maa fi ile gíga ṣe iyanran”, o sọ pe: Lẹ́yìn naa o pẹyin da, mo wa wa nibẹ fun ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà ni o wa sọ fún mi pe: “Irẹ Umar, ǹjẹ́ o mọ onibeere naa?”, mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Jibril ni, o wa ba yin lati kọ yin ni ẹsin yin”.
Muslim gba a waUmar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe Jibril wa ba àwọn saabe ni àwòrán arákùnrin kan ti wọn kò mọ̀. Lára àwọn ìròyìn rẹ ni pe àwọn aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dudu gan, wọn ko ri oripa ìrìn-àjò lára rẹ bii híhàn wàhálà, ati eruku, ati ki irun ri wúruwùru, ati ki aṣọ dọ̀tí, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu awọn ti wọn wa ni ìkàlẹ̀, ti wọn si jókòó ni ọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ni o wa jókòó ni iwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ìjókòó akẹ́kọ̀ọ́, o wa bi i leere nipa Isilaamu, o wa da a lóhùn pẹ̀lú àwọn origun ti o ko fifi ijẹrii mejeeji rinlẹ sínú, ati mimojuto irun wákàtí márùn-ún, ati yíyọ sàká fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i, ati gbigba aawẹ oṣù Ramadan, ati pípé ọranyan hajj fun ẹni tí ó bá ni ikapa. Onibeere wa sọ pé: Òdodo ni o sọ, àwọn saabe wa ṣe eemọ latara ìbéèrè rẹ ti n tọka si àìní imọ rẹ ti o hàn si wọn, lẹ́yìn náà ni o tun wa n sọ pe òdodo ni o sọ. Lẹ́yìn naa ni o bi i leere nipa igbagbọ, o wa da a lóhùn pẹ̀lú àwọn origun mẹ́fà yii ti o ko igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun ati awọn ìròyìn Rẹ sinu, ati ṣíṣe E ni Ọ̀kan pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Rẹ bii dídá ẹ̀dá, ati ṣíṣe E ni Ọkan pẹlu ìjọsìn, ati pe àwọn malaika ti Ọlọhun da latara imọlẹ ẹrú alapọn-ọnle ni wọn, wọn kii yapa àṣẹ Ọlọhun, ati ìgbàgbọ́ nínú àwọn tira ti a sọ̀kalẹ̀ fun awọn ojiṣẹ lati ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, gẹgẹ bii Kuraani, ati Taoreeta, ati Injiila, ati eyi ti o yatọ si wọn, ati ìgbàgbọ́ nínú àwọn ojiṣẹ ti wọn n ba Ọlọhun mu ẹsin Rẹ de ọdọ àwọn èèyàn, ninu wọn ni Nuuh, ati Ibrahim, ati Musa, ati Isa, ìgbẹ̀yìn wọn ni Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a), ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn Anọbi ati awọn Ojiṣẹ, ati ìgbàgbọ́ ninu ọjọ́ ìkẹyìn, ohun ti n bẹ lẹyin ikú ti ko sínú rẹ̀ bii sàréè ati iṣẹmi lẹ́yìn ikú, ati pe wọn maa gbe ọmọniyan dìde lẹ́yìn iku, o si tun maa ṣe ìṣirò, nínú ki ìkángun rẹ jẹ alujanna tabi iná, ati ìgbàgbọ́ pe Ọlọhun ti kádàrá gbogbo nǹkan ni ibamu si ohun ti O ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, ti o si ba ọgbọ́n Rẹ̀ mu ati àkọsílẹ̀ Rẹ, ati fifẹ Rẹ fun un, ati ṣiṣẹlẹ rẹ ni ibamu si ohun ti O kádàrá, ti O si dá a fun un. Lẹyin naa ni o bi i leere nipa ṣíṣe dáadáa, o wa sọ fún un pé ṣíṣe dáadáa naa ni ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ko ba wa le de ipò yii, Ki o yaa maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe Ọlọhun n ri i, akọkọ ni ipò rírí, oun ni o si ga jù, ìkejì ni ipò ìpayà Lẹ́yìn naa o bi i leere pe igba wo ni ayé maa parẹ? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé pe Ọlọhun nikan ni O mọ ìgbà tí ayé maa parẹ, ẹda kankan ko mọ̀ ọ́n, ati ẹni ti wọn n beere nipa rẹ lọ́wọ́ rẹ ni ati ẹni tí n beere. Lẹyin naa ni o bi i leere nipa awọn àmì ti ayé ba fẹ parẹ? O wa ṣàlàyé pe nínú àwọn àmì rẹ ni ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹrú lóbìnrin ati awọn ọmọ wọn, tabi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣiṣẹ ìyá lati ọwọ àwọn ọmọ wọn ti wọn maa ba wọn lo bii ẹrú, wọn maa tẹ́ ayé silẹ fun àwọn adaranjẹ ati awọn tálákà ni ìgbà ìkẹyìn, wọn maa ba ara wọn ṣe iyanran nibi ṣíṣe ilé ni ọ̀ṣọ́ ati kíkọ́ ọ. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé onibeere naa ni Jibril, o wa lati wa kọ́ àwọn saabe ni ẹsin ti o dúró tọ́ yii.
Lati ọdọ 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, wọn maa da a pada ni" Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. O n bẹ fun Muslim pé: "Ẹni ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ko si àṣẹ wa nibẹ, wọn maa da a pada ni"
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu ẹsin tabi ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ẹri kankan ko da le e lori ninu Kuraani ati sunnah, wọn maa da a pada fun ẹni ti o ba ṣe e, ko nii jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ Ọlọhun.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i-: Láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ninu ohun ti o gba wa lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- O sọ pe: “Ẹ̀yin ẹrusin Mi, Emi ṣe abosi ni eewọ fun ara Mi, Mo si ṣe e ni eewọ laarin yin, ẹ ma ṣe abosi si ara yin, ẹ̀yin ẹrú Mi, gbogbo yin ni ẹ sọnù, ayafi ẹni tí Mo ba ṣe imọna fun; nitori naa ẹ wa imọna lọ́dọ̀ Mi, Emi yoo si ṣe amọna yin, ẹyin ẹrú Mi, ebi n pa gbogbo yin ayafi ẹni ti mo ba bọ́; nitori náà, ẹ wá oúnjẹ lọ́dọ̀ Mi, èmi yóò sì bọ́ yín. Ẹ̀yin ẹrú Mi, gbogbo yin ni ẹ wa ni ihoho ayafi eni ti Mo ba da aṣọ bo; nitori naa ẹ wa dida aṣọ bo yin lọ́dọ̀ Mi, maa da aṣọ bo yín, ẹ̀yin ẹrú Mi, ẹ n da ẹṣẹ loru ati ni ọsan, Mo si maa n ṣe aforijin àwọn ẹṣẹ pata, ki ẹ yaa wa aforijin Mi, maa forí jin yin, ẹyin ẹrú Mi, ẹ ko le de ibi ìnira Mi débi pé ẹ maa ni Mi lara, ẹ ko si lee debi anfaani Mi debi pe ẹ maa ṣe mi ni anfaani. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o páyà Ọlọhun jù lọ ninu yin, iyẹn ko le nǹkan kan kun ninu ọla Mi. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o yapa Ọlọhun jù lọ ninu yin, iyẹn ko din nǹkan kan kù ninu ọla Mi. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba dúró lórí ilẹ̀ kan, ki wọn wa maa tọrọ lọ́wọ́ Mi, ki n wa maa fun èèyàn kọ̀ọ̀kan ni ohun ti n beere, ìyẹn ko din nǹkan kan ku ninu ohun ti n bẹ lọdọ Mi, àyàfi gẹgẹ bii ohun ti abẹrẹ maa dinku ti wọn ba ki i bọ inu omi òkun, ẹyin ẹrusin Mi, Mo n ṣe akọsilẹ iṣẹ yin fun yin, lẹyin naa Mo maa san ẹsan rẹ fun yin, ẹnikẹni ti o ba ri oore, ki o dúpẹ́ fun Ọlọhun, ẹni ti o ba si ri yatọ si iyẹn, ki o ma ṣe bu ẹnikan ayafi ara rẹ”.
Muslim gba a waOjiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ṣe alaye pe Ọlọhun Ọba sọ wipe Oun ti ṣe àbòsí ni eewọ fun ara Oun, O si ṣe àbòsí ni eewọ láàrin àwọn ẹ̀dá Rẹ̀; nitori naa ki ẹni kankan má ṣe abosi fun ẹlòmíràn, Ati pe gbogbo ẹda ni o ṣina kúrò ni oju ọna otitọ afi pẹlu itọsọna ati kòńgẹ́ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba beere rẹ lọwọ Ọlọhun, Ọlọhun yoo fun un ni kongẹ ati itọsọna, Ati pe awọn ẹda n bukaata si Ọlọhun, wọn si nilo Rẹ ni gbogbo awọn bukaata wọn, ẹnikẹni ti o ba beere lọwọ Ọlọhun, yoo gbọ́ bukaata rẹ, yoo si tó o, Wọ́n sì ń dẹ́ṣẹ̀ lóru àti ní ọ̀sán, Ọlọhun Ọ̀gá Ògo a sì máa bo àṣírí, a si maa ṣe amojukuro nígbà tí ẹrú bá tọrọ àforíjìn, Wọn ko si ni ikapa lati fi ara ni Ọlọhun tabi ṣe E ni anfaani kankan, Ti wọn ba si wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o paya Ọlọhun ju lọ, ipaya wọn ko ṣe alekun ọlá Ọlọhun, Ti wọn ba si wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o yapa Ọlọhun jù, iyapa wọn ko din nǹkan kan kù ninu ọla Ọlọhun; torí pé ọ̀lẹ ni wọn ti wọn si n bukaata si Ọlọhun ni gbogbo iṣesi ati asiko ati aaye, Oun si ni Ọlọ́rọ̀, mimọ ni fun Un, Ti wọn ba duro ni ààyè kan, èèyàn wọn ati alujannu wọn, akọkọ wọn ati ìkẹyìn wọn, ti wọn wa n tọrọ nǹkan lọ́dọ̀ Ọlọhun, ki O wa maa fun ẹni kọọkan wọn ni ohun ti n beere, ìyẹn ko din nǹkan kan ku ninu ohun ti n bẹ ni ọdọ Ọlọhun, o da bii abẹrẹ ti wọn ba ki i bọ inu òkun, lẹyin naa ki wọn wa mu u jáde, nǹkan kan ko dínkù ninu òkun pẹ̀lú ìyẹn, eléyìí ri bẹ́ẹ̀ tori pípé ọrọ̀ Rẹ, ògo ni fun Un. Ati pe Ọlọhun, mimọ ni fun Un, pa iṣẹ́ awọn ẹru Rẹ mọ, O si ṣe àkọsílẹ̀ wọn, lẹyin naa yoo san wọn ni ẹsan lori rẹ ni Ọjọ Ajinde, ẹni tí ó bá ri ẹsan iṣẹ rẹ ni oore, ki o dúpẹ́ fun Ọlọhun lori pe O fi ṣe kongẹ lati tẹle àṣẹ Rẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rí ẹ̀san iṣẹ́ rẹ̀ ní ohun mìíràn yàtọ̀ sí èyí, kò gbọ́dọ̀ dá ẹnì kan lẹ́bi bí kò ṣe ẹ̀mí rẹ̀ ti maa n pàṣẹ aburu, èyí tí ó mú kí ó pàdánù.
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: “Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun. Mọ pe ti gbogbo ẹda ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe anfaani fun ọ, wọn ko nii ṣe àǹfààní kankan fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Ọlọhun ti kọ fun ọ. Ati pe ti wọn ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe ipalara fun ọ, wọn ko nii ṣe ipalara fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Allah ti kọ fun ọ. Wọn ti gbé àwọn ìkọ̀wé sókè, àwọn tákàdá si ti gbẹ.”
Tirmiziy ni o gba a waIbnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé oun kéré nígbà tí oun n gun nǹkan ọ̀gùn pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa sọ pé: Mo maa kọ ẹ ni àwọn nǹkan kan ti Ọlọhun maa jẹ ki wọn ṣe ọ ni anfaani: Ṣọ́ Ọlọhun pẹlu ṣiṣọ àwọn àṣẹ Rẹ̀ ati jíjìnnà si awọn nǹkan tí O kọ̀, ki O maa ri ọ nibi itẹle àṣẹ Rẹ ati awọn iṣẹ ti a fi n sunmọ Ọlọhun, ki O si má ri ọ nibi awọn ìyapa ati ẹṣẹ, tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀san rẹ ni kí Ọlọ́run dáàbò bò ọ lọ́wọ́ nǹkan ìkórìíra ayé àti ọjọ́ ìkẹyìn, yoo sì ràn ọ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rẹ níbikíbi tí o bá lọ. Ti o ba fẹ tọrọ nnkan, Ọlọhun nikan ni ki o bi; tori pe Oun nikan ni O maa n da onibeere lóhùn. Ti o ba fẹ iranlọwọ, Ọlọhun nìkan ni ki o wa iranlọwọ Rẹ̀. Ki o ni amọdaju pe anfaani kankan ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ará ilẹ̀ kójọ lati ṣe ọ ni anfaani ayafi ohun ti Ọlọhun ba kọ fun ẹ, inira kankan ko si lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ara ilẹ̀ kójọ láti fi ìnira kan ọ àyàfi ohun tí Ọlọhun ba ti kádàrá fun ẹ. Ati pe Ọlọhun ti kọ àlámọ̀rí yii, O si kádàrá rẹ ni ibamu si ọgbọ́n àti imọ Rẹ, ko si àyípadà fun nǹkan ti Ọlọhun kọ.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni o maa kọ̀? O sọ pe: “Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ mi yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá yapa àṣẹ mi ti kọ̀”.
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo ìjọ òun ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀! Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- wa sọ pé: Ta ni ẹni tí ó máa kọ̀ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun?! O da wọn lohun pe: Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa wọ alujanna, ṣùgbọ́n ẹni tí o ba yapa ofin sharia ti kọ̀ lati wọ alujanna pẹ̀lú iṣẹ burúkú rẹ.
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”
Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni ti o ba fara wé àwọn èèyàn kan ninu awọn keferi, tabi awọn arúfin, tabi awọn ẹni rere- pẹ̀lú pe ki o ṣe nǹkan kan ninu awọn ìròyìn ti a mọ̀ wọn mọ̀ nibi adisọkan, tabi awọn ijọsin tabi awọn àṣà - ọkan ninu wọn ni; tori pé àfarawé wọn lóde máa ń yọrí sí àfarawé wọn ní inú, kò sì sí àní-àní pé àfarawé àwọn èèyàn máa ń jẹyọ latara ìjọlójú ni. Ó sì lè jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa gbé wọn tobi, kí wọ́n sì tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn, èyí sì lè mú kí èèyàn máa fara wé wọn titi dori inú ti o pamọ àti ìjọsìn – ki Ọlọhun ṣọ wa kúrò nibẹ-.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ" mo sọ pe: Dajudaju ìyẹn tobi, mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o pa ọmọ rẹ; ti o n bẹru ki o maa jẹun pẹlu rẹ" mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣìná".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ, ó wa sọ pe: Eyi ti o tobi julọ ninu wọn ni ẹbọ ńlá, oun ni ki o wa akẹgbẹ tabi afijọ fun Ọlọhun nibi ijẹ Ọlọhun Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati pe ẹṣẹ yìí, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii ṣe aforijin rẹ afi pẹlu ironupiwada, ti ẹni ti o ba ṣe e ba ku, o maa ṣe gbere ninu ina. Lẹyin naa, ki ọmọniyan pa ọmọ rẹ ni ti ipaya pe ki o maa jẹun pẹlu rẹ, ati pe pipa ẹmi jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni ti wọn pa ba jẹ mọlẹbi ẹni ti o pa ènìyàn, ẹṣẹ rẹ maa tobi bakannaa nigba ti o ba ṣe pe erongba ẹni ti o pa eniyan naa ba pa a nitori ipaya ki ẹni ti wọn pa ma baa ba pin ninu arisiki Ọlọhun. Lẹyin naa, ki ọkùnrin ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣina, bii ki o gbiyanju lati tan iyawo ara adugbo rẹ titi o fi maa ba a ṣe ṣina ti yoo si gbà fun un, Ati pe ṣina jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni tí wọ́n bá ṣe ṣina ba jẹ iyawo ara adugbo ti Sharia pàṣẹ ṣíṣe daadaa si i ati wiwu iwa daadaa si i ati biba a lo lọna ti o daa.
Lati ọdọ Abu Ayyub Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ki Mùsùlùmí yan ọmọ-ìyá rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí lodi kọjá ọjọ́ mẹ́ta, ti wọn maa pade ara wọn, ti wọn ko nii kí ara wọn, wọn ko si nii ba ara wọn sọ̀rọ̀. Ẹni tí ó ni ọlá ju ninu awọn mejeeji ti wọn n jà yii ni ẹni tí o ba n gbìyànjú lati mu odì kúrò, ti o maa wa kọ́kọ́ salamọ, ohun tí a gba lero pẹ̀lú HAJRU nibi ni odì nítorí ìpín ti ẹmi, ṣùgbọ́n odì nítorí tí Ọlọhun, gẹgẹ bii yiyan àwọn ẹlẹṣẹ lódì, ati awọn oni adadaalẹ, ati awọn ọrẹ burúkú, eléyìí ko ni asiko, bi ko ṣe pe o nii ṣe pẹ̀lú anfaani nibi odì, ti o si maa kúrò pẹ̀lú kikuro rẹ.