





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn adari kan maa jẹ lori awọn Musulumi ti wọn ma maa wuwa imọtaraẹninikan pẹlu awọn dukia Musulumi ati eyi ti o yàtọ̀ si i ninu awọn àlámọ̀rí aye, ti wọn ma maa na an gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ, ti wọn ma maa kọ fun awọn Musulumi nibi ẹtọ wọn nibẹ. O si maa waye lati ọwọ wọn, awọn àlámọ̀rí kan ti wọn kọ ninu ẹsin. Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- beere pé: Ki ni awọn maa ṣe nibi isẹsi yẹn? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn pe didana owo wọn ko lee kọ fun yin lati jẹ ki ẹ kọ nnkan ti o jẹ dandan fun yin si wọn ninu gbigbọ ati itẹle, bi ko ṣe pe ki ẹ ṣe suuru ki ẹ si gbọ́ ki ẹ si tẹle,ẹ ko si gbọdọ fa àlámọ̀rí mọ wọn lọwọ, ki ẹ si beere ẹtọ ti o jẹ ti yin lọdọ Ọlọhun, ati pe ki O tun wọn ṣe, ki O si ti aburu wọn ati abosi wọn lọ.
Lati ọdọ An-Nu‘maan ọmọ Basheer - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Apejuwe ẹni ti o duro nibi aala Ọlọhun ati ẹni ti o ko sinu rẹ, da gẹgẹ bi apejuwe awọn ijọ kan ti wọn mu aje lori ọkọ oju-omi, ni apakan wọn wa bọ si oke rẹ ti apakan wọn si wa ni isalẹ rẹ, ti awọn ti wọn wa ni isalẹ rẹ ba ti wa fẹ bu omi mu wọn yio gba ọdọ awọn ti wọn wa l'oke wọn kọja, ni wọn wa sọ pe: Ao ba si lu iho kan si ọdọ wa ki a ma fi fi ṣuta kan awọn ti wọn wa ni oke wa, ti wọn ba fi wọn silẹ pẹlu nkan ti wọn gbero gbogbo wọn maa parun, ti wọn ba wa gba wọn ni ọwọ mu (ti wọn kọ fun wọn) wọn o la (iyẹn awọn ti wọn gbero lati lu iho), ati pe gbogbo wọn pata ni yio la».
Bukhaariy gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi apẹrẹ le'lẹ fun awọn ti wọn duro nibi aala Ọlọhun, awọn ti wọn duro deede lori aṣẹ Ọlọhun, awọn ti wọn n pàṣẹ daadaa, awọn ti wọn n kọ ibajẹ, Ati pe apejuwe awọn ti wọn ko sinu awọn aala Ọlọhun ti wọn n fi daadaa silẹ, ti wọn n wu iwa ibajẹ, ati oripa iyẹn nibi lila awujọ, da bi apejuwe ijọ kan ti wọn gun ọkọ oju-omi, ni wọn wa mu aje lati mọ awọn ti wọn maa jokoo si oke ọkọ oju-omi ati awọn ti wọn maa jokoo si isalẹ rẹ, ni awọn kan wa wa ni oke rẹ, ti awọn kan si wa ni isalẹ rẹ, ti awọn ti wọn wa ni isalẹ ba wa fẹ pọn omi wọn a lọ si ọdọ awọn ti wọn wa ni oke wọn, Ni awọn ti wọn wa ni isalẹ wa sọ pe: Ti awa ba le lu oju kan ni aaye wa ni isalẹ ti a maa ti ibẹ mumi, ki a ma baa maa ni awọn ti wọn wa ni oke wa lara, ti awọn to wa l'oke ba fi wọn silẹ lati ṣe nkan yẹn, ọkọ oju-omi yẹn a tẹ gbogbo wọn ri, ṣugbọn ti wọn ba dide lati kọ fun wọn nibi iyẹn, awọn ijọ mejeeji ni yio la papọ.
Lati ọdọ Abu Bakr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, ẹ maa n ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na), mo si gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn".
Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah ati AhmadAbu Bakr As-Sideeq- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan a maa ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na)(Al-Maa'ida: 105). Ti wọn maa wa gbọye ninu rẹ pe dajudaju igbiyanju jẹ dandan lori ọmọniyan lori titun ara rẹ ṣe nikan, ati pe ìṣìnà ẹni ti o ṣina ko nii ko inira ba a lẹyin ìyẹn, ati pe wọn ko wa lati ọdọ wọn pipáṣẹ daadaa ati kikọ iwa ibajẹ! ni o wa fi mọ wọn pe ko ri bayẹn, pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa a- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi ti wọn ko si kọ fun un kuro nibi abosi ṣíṣe rẹ, ti agbara lori kikọ fun un si n bẹ lọdọ wọn, ó maa ku díẹ̀ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari gbogbo wọn, ẹni ti o n ṣe ibajẹ ati ẹni ti o n dakẹ nipa rẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ, gbogbo ọjọ ti oorun ba ti n yọ ti o ba n ṣe deede laarin eeyan meji saara ni, ati pe ki o ran ẹnikan lọwọ l'ori nkan ọ̀gùn rẹ, boya ki o gbe e gun un tabi ki o gbe ẹru rẹ fun un lori rẹ saara ni, ati pe ọrọ daadaa saara ni, ati gbogbo igbesẹ ti o ba n gbe lọ sí ibi irun saara ni, ki o si tun maa mu nkan ti o le ṣe eeyan ni ṣuta kuro l'ọna saara ni»
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan l'ori gbogbo musulumi ti o ni iwọ ni ọrùn ni ojoojumọ pẹlu onka gbogbo ibi tí àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara rẹ lati maa ṣe saara, ti yio ṣe e fun Ọlọhun lati fi dupẹ alaafia, ati pe o ṣe awọn ibi ipadepọ àwọn eegun rẹ ni nkan ti o jẹ ki o rọrun fun un lati ka a kò ati lati nà án, Ati pe dajudaju saara yẹn yio maa jẹ ṣiṣe pẹlu gbogbo iṣẹ daadaa patapata, ko si mọ nibi ifunni ni owo nikan, ninu rẹ naa sì ni: Deede rẹ ati atunse rẹ laarin awọn onija meji saara ni, Ati pe saara n bẹ nibi iranlọwọ rẹ fun ẹni ti o kagara nibi nkan ọ̀gùn rẹ ti waa wa gbe e gun un tabi ki o na ọwọ ẹru rẹ fún un, Ati pe ọrọ ti o daa bii iranti ati adua ati salamọ ati eyi ti o yatọ si i saara ni, Ati pe gbogbo igbesẹ kọọkan ti o ba n gbe lọ s'ibi irun saara ni, Ati pe mimu nkan ti o le ṣeni ni ṣuta kuro l'ọna saara ni.
Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik – ki Allāh yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o dara julọ ni iwa.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o pe julọ ni iwa, o si tun gba iwájú nibi gbogbo iwa ati nkan daadaa, nibi ọrọ to daa, ati ṣiṣe daadaa, ati titu oju ka, ati mimu suta kuro ati nini atemọra rẹ lati ọdọ ẹlòmíràn.
Sa‘d ọmọ Hishām ọmọ ‘Āmir sọ – nigba ti o wọlé tọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i pé-: Irẹ iya awa mu’mini, fun mi ni iro nipa iwa Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o sọ pe: Ṣe iwọ o ki n ka Alukurāni ni? Mo sọ pe: Mo maa n ka a, o sọ pe: Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani.
Muslim ni o gba a wa nibi akojọpọ hadiisi kan ti o gunWọn bi iya awa mu’mini ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i – leere nipa iwa Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o si fún wọn ní esi pẹlu gbólóhùn ṣókí kan ti o ko nkan ti o pọ sinu, o si tun ṣẹri onibeere sibi Kuraani Alapọn-ọnle eleyii ti o ko gbogbo iroyin ti o pe sinu, nígbà náà ni o wa sọ pe: O jẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹni tí maa n wuwa pẹlu awọn iwa Alukurāni. Alukurāni o nii pàṣẹ pẹlu nkankan ayaafi ki o ṣe é, ko si nii kọ kuro nibi nkankan ayaafi ki o jina si i, nitori naa iwa rẹ ni ṣiṣe iṣẹ pẹlu rẹ (Alukurāni), ati diduro nibi awọn aala rẹ, ati lilo ẹkọ pẹlu awọn ẹkọ rẹ, ati ṣiṣe ariwoye pẹlu awọn àkàwé rẹ àti awọn itan rẹ.
Lati ọdọ iya awọn olugbagbọ ododo, A'isha ki Ọlọhun bawa yọnu sì i, o sọ bayi pe: Mi o ri ki anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba - ki o fi gbogbo ara rẹrin titi ti maa fì wá rí bèlúbèlú rẹ̀, ṣugbọn Anọbi aa máa rẹrin musẹ.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niKi Ọlọhun bá wa yọnu si A'isha, Oun ló fún wa niro pe Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - Kii mọn fi gbogbo ara rẹrin ti a fi waa rí belubelu rẹ, (belubelu ni ẹran ti o so mọ oke ọ̀nà ọ̀fun) ṣugbọn Anọbi aa maa rẹrin musẹ.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mālik ọmọ Buhayna - ki Ọlọhun yọnu si i -: Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba n kirun yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji titi ti abiya rẹ mejeeji o fi han.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fi ori kanlẹ yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji ni iforikanlẹ; yoo si gbe ọwọ kọọkan jina si ibi ẹgbẹ ti o wa, gẹgẹ bii iyẹ meji, titi ti awọ abiya rẹ fi maa han; Ati pe eyi n bẹ ninu jijẹ ki apá méjèèjì da bii iyẹ ati gbigbe wọn jìnà gan si ẹgbẹ rẹ mejeeji.
Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ bayi pe: Ti ki báa ṣe pe kin má ko waala bá awọn olugbagbọ ododo ni - tabi awọn ijọ mi ni - mi o ba pa wọ́n laṣẹ lati máa rin pako ni gbogbo asiko Irun kọọkan.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnnabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a fún wa niro pe, ti ki baa ṣe ìbẹrù waala fún awọn olugbagbọ ododo ninu awọn ijọ rẹ̀, ko ba ṣe ni dandan fun wọn lati ma run pako ni gbogbo igba ti wọ́n ba fẹ kirun.