





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni ni iro pe: Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n gba tituuba awọn ẹru rẹ, ti ẹru ba da ẹṣẹ kan ni ọsan ti o si tuuba ni oru Ọlọhun o gba tuuba rẹ, ti o ba si da ẹsẹ ni oru ti o wa tuuba ni ọsan Ọlọhun a gba tuuba rẹ, Ọba ti mimọ n bẹ fun Un maa n tẹ ọwọ Rẹ fun tuuba ni ti ìdùnnú si i ati gbigba a, ati pe ilẹkun tituuba o yẹ ni nkan ti wọn maa ṣi silẹ titi oorun o fi yọ nibi ti o ti n wọ ni ti ikede titan ayé, ti o ba ti wa yọ dajudaju ilẹkun tituuba ti di titi niyẹn.
Lati ọdọ Abu Dardā'i - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ».
Abu Daud ati Tirmiziy ni wọn gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju nkan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ninu awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ni iwa daadaa, ati pe ìyẹn n bẹ pẹlu titu oju ka, ati kika ṣuta kuro, ati ṣiṣe daadaa. Ati pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga korira ẹni ti ko dara nibi iṣe rẹ ati ọrọ rẹ, ẹni ti maa n fi ahọn rẹ sọ ibajẹ.
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n ṣe adua lọpọlọpọ pẹ̀lú àwọn adua ṣókí tí o ko nǹkan ti o pọ sinu, ninu rẹ ni: «Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná» Ó ko oore ayé sínú, bíi ìpèsè arisiki ti o rọrun ti o gbooro, ti o jẹ alaali, ati ìyàwó ti o daa, ati ọmọ itutu ojú, ati ìsinmi, ati ìmọ̀ tí ó wúlò, ati iṣẹ́ rere, àti ohun tí ó jọ ìyẹn ninu awọn ohun ti èèyàn n fẹ ati ohun ti wọn ṣe ni ẹtọ, ati daadaa alukiyaamọ bii lila nibi awọn iya sàréè, ati ibuduro ni ọjọ igbende, ati iná, ati riri iyọnu Ọlọhun, ati nini idẹra gbere, ati isunmọ Oluwa Ajọkẹ-aye.
Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –: “Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbii laa ilaaha illaa anta, khalaqtanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wawahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sanahtu, abuuhu laka binihmatika alayya, wa abuuhu bizambii, fagfir lii, fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta", o sọ pe: Ẹni ti o ba sọ ọ ni aarọ ti o si ni amọdaju pẹlu ẹ, ti o wa kú, ni ọjọ naa ki o to di irọlẹ, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna, ẹni tí ó bá sọ ọ ni alẹ ti o si ni amọdaju pẹ̀lú ẹ, ti o wa kú ki ilẹ o to mọ́, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna".
Bukhaariy gba a waOjiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe: Awọn gbolohun kan wa fun wíwá idarijin, ati pe eyi ti o dara ju ti o si tobi ju ninu wọn ni ki ẹru maa sọ pe: "Allahummọ anta Robbii laa ilaaha illaa anta, khalaktanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wa wahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sonahtu, abuuhu laka binihmatika alayya wa abuuhu bizambii fagfir lii fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta" Ẹru maa fi taohid rinlẹ fun Ọlọhun ni akọkọ, ati pe Ọlọhun ni O da a, Oun si ni yoo maa jọ́sìn fun ti ko si orogun fun Un, ati pe oun wa lori ohun ti o ṣe adehun rẹ fun Ọlọhun bii ini igbagbọ si I ati itẹle E ni ibamu si ikapa rẹ; torí pé ko si bi ẹrú ṣe le sin Ọlọhun tó, ko le ni ikapa lati ṣe gbogbo nnkan ti Ọlọhun pa a láṣẹ ki o ṣe, bẹ́ẹ̀ si ni ko lee kapa lati dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ bi o ṣe yẹ, o si maa sadi Ọlọhun, o si tun maa dirọ mọ ọn, torí pé Oun ni Ẹni tí a maa n sadi kuro nibi aburu ti ẹrú ba ṣe, Ó maa fi rinlẹ ó sì maa jẹ́wọ́ ìbùkún rẹ̀ fún un, ó sì maa padà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípa fifirinlẹ àti jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìgbọràn rẹ̀, Lẹ́yìn ẹ̀bẹ̀ ipada si ọdọ Ọlọ́run yìí, ó maa bẹ Olúwa rẹ̀ pé kí O forijìn òun nípa bíbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, kí O sì dáàbò bò òun kuro nibi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú àforíjìn, oore àti àánú Rẹ̀, nítorí pé kò sẹ́ni tó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn, àfi Òun, Ọba ti O lágbára ti O gbọnngbọn. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe o wa ninu awọn asikiri àárọ̀ ati alẹ, ẹni tí ó bá sọ ọ pẹ̀lú amọdaju ati ìrántí àwọn ìtumọ̀ rẹ̀, ati ini igbagbọ si i ni aarọ ọjọ́ naa, laarin yiyọ oorun si yiyẹ àtàrí rẹ, oun naa ni àsìkò ọsan, ti o wa ku, o maa wọ alujanna, Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ ní alẹ́, láti ìwọ̀ oòrùn títí di àfẹ̀mọ́jú, tí ó sì kú kí ilẹ o to mọ́, yóò wọ alujanna.
Lati ọdọ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ẹ paya abosi, nitori pe abosi jẹ awọn okunkun ni ọjọ igbedide, ẹ paya ahun, nitori pe ahun lo pa awọn ti wọn ṣáájú yin run, o ti wọn lati maa ta awọn ẹjẹ wọn silẹ wọn si sọ awọn eewọ wọn di ẹtọ"
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ kuro nibi abosi, ninu rẹ ni: Ṣíṣe abosi awọn eniyan ati abosi ara ẹni ati ṣíṣe abosi nibi iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Oun ni gbigbe funfun ẹni ti o ni ẹtọ ni ẹtọ rẹ ju silẹ, ati pe ṣíṣe abosi jẹ okunkun fun awọn ti wọn n ṣe e ni ọjọ igbedide latara ṣiṣẹlẹ awọn ile koko ati awọn ibẹru, O tun kọ kuro nibi ash-shuhhu, oun ni eyi ti o le koko ninu ahun pẹlu ojúkòkòrò, ninu rẹ ni aṣeeto nibi pipe awọn iwọ ti owo ati ilekoko ojúkòkòrò lori aye, Ati pe iran yii ninu abosi ti pa awọn ti wọn ṣíwájú wa run ninu awọn ijọ, nigba ti o ti wọn lọ sibi pipa awọn kan ninu wọn, ati ṣíṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe leewọ ninu awọn nnkan eewọ lẹtọọ.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -: Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Awọn iwa Isilaamu wo lo fi n lọla julọ? Ni o wa darukọ awọn iwa meji: Alakọkọọ: Pipọ ni imaa fun awọn alaini ni ounjẹ, ti saara ati ẹbun ati igbalejo ati ikolẹnujọ sì tun wọ inu rẹ, ati pe ọla ifunni l'ounjẹ tun kanpa ni awọn asiko ebi ati ọwọn gogo. Ẹlẹẹkeji ni: Sisalamọ si gbogbo musulumi, o mọ ọn ni tabi o ko tiẹ mọ ọn.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan».
Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a waSaabe abiyi tii ṣe Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - n funni niroo pe: Awọn jade ni alẹ kan ti ojo pọ gan ti okunkun naa si dudu kirikiri, lati lọ wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-; ki o le ki irun fun wọn, ti wọn si ri i, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: "Qul" iyẹn ni pe: ka, ko si ka nkankan, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tun ọrọ rẹ wi fun un, ni Abdullāh wa sọ pe: Kini ki n ka irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Ka suuratul Ikhlaas {Qul Uwal Laahu ahad}, ati Al-Mu‘awwidhatayn {Qul a‘uudhu bi robbil falaq}, ati {Qul a‘uudhu bi robbin naas}, ni asiko irọlẹ, ati asiko aarọ, ni ẹẹmẹta yio maa sọ ọ kuro nibi gbogbo aburu, ti yio si la ọ kuro nibi gbogbo ibajẹ.
Lati ọdọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Larubawa oko kan wa ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Kọ mi ni ọrọ kan ti maa maa sọ ọ: O sọ pe: " Sọ pe: Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, Allahu Akbar kabeeran, wal amdulillah katheeran, Subhaanallah Robbil 'aalameen, laa haola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem" o sọ pe: Awọn wọnyi jẹ ti Oluwa mi, ki ni o jẹ temi? O sọ pe: Sọ pe: Allahumo igfir liy warhamniy wahdiniy warzuqniy".
Muslim gba a waArakunrin kan ninu awọn ti wọn n gbe oko beere lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati kọ oun ni iranti kan ti o ma maa sọ ọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Sọ pe: "Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu" o bẹ̀rẹ̀ pẹlu jijẹrii imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ìtumọ̀ rẹ ni pe ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, "Allahu Akbar kabeeran" O n túmọ̀ si pe: Ọlọhun tobi ju gbogbo nnkan lọ O si ga ju wọn lọ, "Wal amdulillah katheeran" O túmọ̀ si pe: Ọpẹ ni fun Ọlọhun ni eyi ti o pọ, lori awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ ati awọn idẹra Rẹ ti ko ṣee ka, "Subhaanallah Robbil 'aalameen" O túmọ̀ si pe: O mọ kuro nibi adikun, "Laa aola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem" O túmọ̀ si pe: Ko si ìyípadà lati isẹsi kan si isẹsi miiran afi pẹlu Ọlọhun ati iranlọwọ Rẹ ati ifiniṣe-kongẹ Rẹ, Arakunrin naa sọ pe: Awọn ọrọ wọnyii jẹ ti Oluwa mi lati ṣe iranti Rẹ ati gbigbe E tobi, ki ni o wa fun mi ninu adura fun ara mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Sọ pe: "Allahumo igfir liy", Ọlọhun mi, fori jin mi Pẹlu pipa awọn aburu rẹ ati bibo o, "Warhamniy" ki O si kẹ mi Pẹlu mimu awọn anfaani ti ọrun ati ti aye ba mi, "Wahdiniy" ki O si tọ mi sọ́nà Si eyi ti o dara julọ ninu awọn isẹsi ati si oju ọna taara, "Warzuqniy" ṣe arisiki fun mi Pẹlu owo halaali ati alaafia ati gbogbo oore ati alaafia.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Awọn iran eniyan meji kan wa ninu ara ina ni wọn, mi ko ri wọn, ijọ kan ni ti awọn ọrẹ n bẹ pẹlu wọn ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maluu ti wọn maa n fi i na awọn eniyan, ati awọn obinrin kan wọn maa wọ aṣọ wọn si maa wa ni ihoho, ti wọn maa n mu ẹlòmíràn yẹ gẹrẹ, ti awọn gan ti yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, awọn ori wọn da gẹgẹ bii ike ẹyin màlúù ti o n yẹ, wọn ko nii wọ alujanna, wọn ko si nii gbọ́ oorun rẹ, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn ti maa n ri i lati irin bayii bayii ".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣekilọ kuro nibi awọn iran eniyan meji kan ninu awọn ara ina, ko ri wọn, wọn ko si si ni igba aye rẹ, sugbọn wọn maa wa lẹyin rẹ: Iran akọkọ: Awọn ijọ kan ti awọn ọrẹ ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maalu ti wọn gun n bẹ lọwọ wọn, wọn maa n fi i na awọn eniyan, awọn ni awọn ọlọpaa ati awọn ti wọn n kun àwọn alabosi lọ́wọ́, àwọn ti wọn maa n na awọn eniyan lọna ailẹtọọ. Ati pe iran ikeji ni: Awọn obinrin kan ti wọn ti bọ aṣọ iparamọ ati itiju eyi ti wọn sábà maa n ṣẹda obinrin lori rẹ. Iroyin wọn ni: Wọn maa wọ aṣọ lódodo, wọn maa wa ni ihoho ni ìtumọ̀; nitori pe wọn wọ aṣọ ti o fẹlẹ ti o n ṣe iroyin ara, wọn si bo apakan ninu ara wọn, ti wọn ṣi apakan rẹ kalẹ; ni ti afihan ẹwà, Ti wọn maa n yi awọn ọkan awọn ọkunrin sọ́dọ̀ wọn pẹlu aṣọ wọn ati ìrìn akọ wọn, ti wọn maa n yẹ awọn ejika wọn, ti wọn maa n yi awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn lọ sibi iyẹgẹrẹ ati iyipada ti awọn ko si, Ninu awọn iroyin wọn ni pé: Awọn ori wọn da gẹgẹ bii ike ẹyin rakunmi ti o tẹ, wọ́n maa n jẹ ki orí wọn tobi pẹ̀lú wiwe aṣọ mọ́rí ati ohun ti o jọ ọ. Ati pe afiwe pẹlu ike ẹyin ràkúnmí rí bẹ́ẹ̀ fun lilọ soke irun wọn ati awọn irun-dídì wọn sórí wọn, ati lílọ́ rẹ pẹlu nnkan ti wọn fi dì í titi o fi maa tẹ̀ si ẹgbẹ kan ni ori gẹgẹ bii ike maalu ṣe maa n tẹ si ẹgbẹ kan. Ẹni ti o ba wa pẹlu awọn iroyin yii, a jẹ pe adehun iya ti o le koko yii n bẹ lara wọn pẹlu pe ki wọn ma wọ alujanna ki wọn si ma gbọ́ oorun rẹ ki wọn si ma sunmọ ọn, ati pe oorun alujanna wọn maa n gbọ́ ọ lati ọna ti o jinna.