





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Sahl ọmọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ọjọ́ Khaibar pé: Dajudaju maa fun arakunrin kan ni asia yii ni ọla ti Ọlọhun maa ti ipasẹ rẹ fun wa ni iṣẹgun, o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa nífẹ̀ẹ́ rẹ”, o sọ pe: Àwọn ènìyàn sùn ní alẹ́ náà tí wọ́n ń jiroro laarin ara wọn tani wọn yoo fun.” Nígbà ti ilẹ̀ mọ́, àwọn èèyàn lọ ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ọkọọkan ninu wọn si n fẹ ki wọn fun oun, o sọ pe: “Ibo ni ‘Ali ọmọ Abu Talib wà”? Wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ojú n dùn ún. O sọ pe: “Ẹ ranṣẹ si i”, wọn si mu u wa ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa tutọ́ si oju rẹ mejeeji, o si ṣe adura fun un, o si gbadun gẹgẹ bii pe inira kan kan ko mu u, o wa fun un ni asia náà. Ali wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki n maa ba wọn ja titi wọn fi maa da bii wa? O sọ pe: “Maa lọ ni pẹlẹpẹlẹ titi waa fi dé agbegbe wọn, lẹyin naa pe wọn sinu Isilaamu, sọ nnkan ti o jẹ dandan le wọn lori ninu ẹtọ Ọlọhun fun wọn nibẹ. Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun awọn saabe nípa ìṣẹ́gun awọn mùsùlùmí lori awọn Juu Khaibar ni ọjọ keji, ìyẹn maa waye lati ọwọ arakunrin kan ti oun maa fun un ni asia, oun naa ni àsíá tí àwọn ọmọ ogun maa n fi ṣe àmì wọn, Ati pe arakunrin yii ninu awọn iroyin rẹ ni pe o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa si nífẹ̀ẹ́ rẹ, Àwọn saabe si sùn ni alẹ ti wọn n jíròrò ti wọn si n sọ̀rọ̀ nipa pe tani wọn maa fun ni asia naa? Ni ti ìfẹ́ si iyì ńlá yii, Nigba ti o di àárọ̀ wọn lọ sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, gbogbo wọn ni wọ́n n nírètí pé àwọn á gba iyì yìí, Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa beere nipa 'Ali ọmọ Abu Talib- ki Ọlọhun yọnu si i-? Wọn sọ pé: O rẹ ẹ, ojú rẹ mejeeji n dun un. Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ranṣẹ si i, wọn si de pẹlu rẹ, o wa tu itọ si oju 'Ali mejeeji ninu itọ rẹ abiyi, o ṣe adura fun un, o si gbádùn nibi aisan rẹ, o wa da gẹgẹ bii pe inira kan ko mu u tẹ́lẹ̀, o wa fun un ni asia naa, o pa a láṣẹ pẹlu pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ titi o fi maa sunmọ aaye ààbò awọn ọta ti o si maa fi gbigba Isilaamu lọ wọn, ti wọn ba da a lohun; o maa sọ fun wọn nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn ọran-anyan. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé fun 'Ali nipa ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ si oju ọna Ọlọhun ati pe ti ipepe ba jẹ okunfa ìtọ́sọ́nà arakunrin kan ṣoṣo ìyẹn loore fun un ju ki rakunmi pupa jẹ tirẹ̀ lọ, eyi ti o ṣe pe oun ni o níye lórí julọ ninu awọn dukia larubawa, yio ni i tabi ki o fi ta ọrẹ.
Lati ọdọ Yahya ọmọ 'Umaaroh Al-Maaziniy o sọ pe: Mo ri ti Amru ọmọ Abu Hasan bi Abdullahi ọmọ Zaid leere nipa aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni o ba beere fun igba kan ti omi wa ninu ẹ, o ṣe aluwala fun wọn ni aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o da omi si ọwọ rẹ lati inu igba, o fọ ọwọ rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ inu igba, o fi omi yọ ẹnu o si fa a simu, O si fa a sita, ni gẹẹ mẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ ọ, o si fọ oju rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o fọ ọwọ rẹ mejeeji ni ẹẹmeji titi de igunpa mejeeji, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ ọ, o si pa ori rẹ, o gbe mejeeji lọ si ẹyin ati ṣíwájú ni ẹẹkan, lẹyin naa, o fọ ẹsẹ rẹ mejeeji titi de kokosẹ
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAbdullahi ọmọ Zaid- ki Ọlọhun yọnu si i- ṣàlàyé bi aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ri, pẹlu aworan ti iṣẹ, Ni o ba beere fun igba kekere kan ti omi wa ninu ẹ, O kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, lẹyin naa o tẹ igba naa o si da omi, o si fọ mejeeji lẹẹmẹta si ita igba naa, Lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ inu igba, o si bu omi gẹẹ mẹta, ti o n yọ ẹnu ninu gbogbo gẹẹ kọọkan ti o si n fin omi si imu ti o si n fin in sita pada, Lẹyin naa o bu omi ninu rẹ ti o si fọ oju rẹ lẹẹmẹta, Lẹyin naa o bu omi ninu rẹ ti o si fọ ọwọ rẹ mejeeji titi de igunpa mejeeji ni ẹẹmeji ẹẹmeji, Lẹyin naa, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba ti o si pa ori rẹ pẹlu ọwọ rẹ lati ibi ti irun rẹ ti bẹ̀rẹ̀ titi ti o fi de ipakọ rẹ ni oke ọrun, lẹyin naa, o da mejeeji pada titi o fi de aaye ti o ti bẹ̀rẹ̀ nibẹ, Lẹyin naa, o fọ ẹsẹ rẹ mejeeji pẹlu kokosẹ mejeeji.
Lati ọdọ Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran mi ni iṣẹ kan, ni mo ba ni janaba ti mi o si ri omi, ni mo ba po ara mọ erupẹ gẹgẹ bi ẹranko ṣe maa n po ara mọ ọn, lẹyin naa ni mo wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni mo si sọ iyẹn fun un, o si sọ pe: «O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ si irin-ajo kan fun awọn bukaata rẹ kan, ni janaba ba ṣẹlẹ si i latara ibalopọ tabi dida atọ pẹlu adun, ti ko si ri omi ti yíò fi wẹ, O jẹ ẹni ti ko mọ idajọ tayammam (Aluwala eleepẹ) fun janaba, amọ o mọ idajọ rẹ fun ẹgbin kekere, Ni o ba gbiyanju ti o si lero pe gẹgẹ bi o ṣe maa fi iyẹpẹ ti o wa ni ori ilẹ pa awọn orike aluwala kan nibi ẹgbin kekere, nitori naa tayammam fun janaba naa gbọdọ ṣẹlẹ pẹlu fifi iyẹpẹ kari gbogbo ara; lati fi ṣe deede omi, ni o ba yi ara mọ iyẹpẹ titi ti o fi kari ara ti o si lọ kirun, Nigba ti o wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o sọ iyẹn fun un; ki o le mọ boya o wa loju ọna abi bẹẹkọ? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye fun un bi a ṣe n ṣe imọran kuro nibi ẹgbin mejeeji kekere gẹgẹ bii itọ, ati ńlá gẹgẹ bii janaba: Oun naa ni ki o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ki o pa osi lori ọtun, ki o fi pa ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ.
Lati ọdọ Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo Musulumi.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niSaabe Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe oun dunnimọ oun si ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo ati pipe awọn irun maraarun-un ti wọn jẹ ọran-anyan ni ọsan ati alẹ, pẹlu awọn majẹmu rẹ ati awọn origun rẹ ati awọn dandan rẹ ati awọn sunnah rẹ, ati lori pipe saka ti a ṣe ni ọran-anyan, oun ni ijọsin ti owo ti o jẹ dandan, ti wọn maa n gba lọwọ awọn ọlọrọ ti wọn si maa n fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ninu awọn alaini ati awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn, ati lori itẹle fun awọn adari, ati iṣiti fun gbogbo Musulumi, ìyẹn pẹlu ṣíṣe ojúkòkòrò láti ṣe e ni anfaani, ati mimu daadaa de ọdọ rẹ, ati titi aburu danu fun un pẹlu ọrọ ati iṣẹ.
Lati ọdọ Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo ṣafẹku ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) lori ibusun loru ọjọ kan, mo wa nfi ọwọ wa a kiri bẹẹni ọwọ mi kan inu atẹlẹsẹ rẹ nigbati o wa ni iforikanlẹ, ti o gbe gigisẹ rẹ mejeeji sí oke, ti nsọ bayi ninu adura rẹ pe: "irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ.
Muslim gba a waAishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: mo sun lẹgbẹ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), mo ṣe afẹku rẹ ni oru (mi o ri), mo wa fi ọwọ mi woo ni ààyè ti o ma ti nkirun ninu yàrá, bayi ni mo kan lojiji pe o nkirun lọwọ ti gigisẹ rẹ mejeeji si wa ni iduro, bẹẹ sì ni o nsọ bayi pe: (mo nwa isọ) mo nṣe atẹgun sọdọ Rẹ (pẹlu ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ) sí mi tabi sí awọn ijọ mi, (ati) pe mo nwa isọra (pẹlu amojukuro Rẹ) ati amojukuro re ti o pọ (kuro nibi ijẹniya Rẹ), (mo wa idaabobo lọdọ Rẹ pẹlu araarẹ) ati pẹlu awọn iroyin rirẹwa Rẹ lọdọ awọn iroyin titobi Rẹ, nigbati o jasipe ẹnikan ò lee ṣọ ni lọdọ Rẹ àyaàfi ìwọ fún rara Rẹ, kò sibi aa salọ fún akoyọ, bẹẹ sì ni kò sibi ti a le sadi lati sa fún Ọlọhun ayaafi ki a sadi Ọlọhun, (Mi o le ṣe onka ẹyin fún irẹ Ọlọhun), mi o nikapa, mi o sì lè dé òpin ati onka lati ka gbogbo idẹra Rẹ tan nitori ikagara mi, bẹẹ ni mi o le ka daada Rẹ tan gẹgẹbi O ṣe lẹtọ si i, koda bi mo ba ṣe igbiyanju ati akitiyan láti ṣe bẹẹ, (gẹgẹ bí Irẹ Ọlọhun ṣe ṣe ẹyìn fún ara Rẹ) Iwọ ni O ṣe ẹyìn fún Pàápàá ara Rẹ, ẹyin ti o ba ọ mu, taani ẹni náà tí o ni ikapa lati mu ẹyin Rẹ wá ní bo ṣe yẹ?!
Lati ọdọ shureih ọmọ Haani'i o sọ pé: Mo bi Aishah leere, mo sọ pé: kini nkan akọkọ ti Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) ma nṣe ti o ba wọlé rẹ? Aishah daun pe: yoo kọkọ rin pako.
Muslim gba a waO tiwa ninu imọna Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati Ọla Rẹ máa ba a) pé kí o kọkọ rin pako ti o ba wọlé rẹ ni eyi keyi asiko ni oru tabi ọsan.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mashood - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Wọn sọ nípa ọkunrin kan lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti o sun lati alẹ titi ilẹ fimọ, Anobi sọ pé: "arakunrin naa ni èṣù (Satani) ti tọsi inu eti rẹ méjèejì, tabi o sọ pé: sinu eti rẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn darukọ ọkunrin kan lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti o sun titi ti ilẹ fi mọ ti orun fi yọ ti kò si dide kirun ọranyan, ni Anabi ba sọ pe: oun ni arakunrin kan ti èṣù (Satani) ti tọ sí inu eti rẹ.
Lati ọdọ Ma'daan ọmọ Abu Tolha Al-Ya'mariy o sọ pe: Mo pade Thaobaan ẹru ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mo wa sọ pe: Fun mi ni iro nipa iṣẹ kan ti mo ba n ṣe e Ọlọhun maa fi mu mi wọnu alujanna? Tabi o sọ pe mo sọ pé: pẹlu eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ ninu awọn iṣẹ, o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni ẹẹketa, o wa sọ pe: Mo beere nipa ìyẹn lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ" Ma'daan sọ pe: Lẹyin naa mo pade Abu Dardaa mo si bi i leere, o si sọ fun mi: Iru nnkan ti Thaobaan sọ fun mi.
Muslim gba a waWọn beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa iṣẹ ti o maa jẹ okunfa fun wiwọnu alujanna tabi nipa eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun olubeere pe: Dunni mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iforikanlẹ nibi irun, o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ kan afi ki O fi gbe ẹ ga nípò, ki O si fi i ṣe aforijin fun ẹ.
Lati ọdọ Aishah iya awọn olugbagbọ ododo, ki Ọlọhun yọnu si i: Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba) aa maa se igbiyanju ni mẹwa igbẹyin iru igbiyanju ti kii se ninu awọn ọjọ miran.
Muslim gba a waTi mẹwa igbẹyin ninu osu Ramadan ba tide Anọbi (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) aa maa gbiyanju ninu rẹ pẹlu ìjọsìn ati itẹle aṣẹ Ọlọhun, aa si maa se ọpọlọpọ awọn oriṣirisi iṣẹ o loore ati awọn oníranran iṣẹ daada ati ìjọsìn fún Ọlọhun eyi ti o pọ ju bi se ma ngbiyanju ni awọn ọjọ míràn lọ, ori bẹẹ nitori titobi ati ọlá ti nbẹ fún awọn òru náà ati nítorí wiwa òru abiyi.