





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe- An-Nuhmaan wa na ìka rẹ méjèèjì si etí rẹ méjèèjì-: “Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn, o wa n bẹ láàrin àwọn méjèèjì àwọn nǹkan ti wọn ruju, ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ko si mọ wọn, ẹni tí ó bá ṣọra fun awọn iruju naa, o ti wa mímọ́ fun ẹsin rẹ ati ọmọlúwàbí rẹ, ẹni tí o ba ko sinu àwọn ìríjú naa, yoo ko sinu nǹkan eewọ, o da gẹgẹ bii adaranjẹ̀ ti n da ẹran jẹ̀ ni etí ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò, o sunmọ ki o da ẹran wọ inu rẹ. Ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú gbogbo ọba ni o ni ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò. Ẹ tẹti ẹ gbọ, ilẹ Ọlọhun ti a da ààbò bò ni àwọn nǹkan ti O ṣe ni eewọ, ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú baaṣi ẹran kan n bẹ nínú ara, ti o ba ti dáa, gbogbo ara ti dáa, ti o ba si ti bajẹ, gbogbo ara ti bajẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ, oun naa ni ọkàn”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé òfin kan ti o kárí nibi awọn nǹkan, o si pin si mẹta ninu ṣẹria: Ẹ̀tọ́ ti o fi ojú hàn, ati eewọ ti o fi ojú hàn, ati awọn alamọri kan ti wọn ruju ti idajọ wọn kò hàn nipa pe ṣe ẹtọ ni abi eewọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu awọn èèyàn ko mọ idajọ wọn. Ẹni ti o ba gbe àwọn nǹkan iruju yẹn jù silẹ, ẹsin rẹ maa ni àlàáfíà pẹ̀lú jíjìnnà sí kiko sinu nǹkan eewọ, ọmọlúwàbí rẹ naa si maa ni àlàáfíà kuro nibi ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn pẹ̀lú nǹkan ti wọn yoo fi maa bu u ti o ba ṣe nǹkan ìríjú yii. Ẹni ti ko ba jìnnà si awọn nǹkan ìríjú, ninu ki o ko sinu nǹkan eewọ, tabi ki àwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ọmọlúwàbí rẹ. Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àkàwé kan lélẹ̀ lati ṣàlàyé iṣesi ẹni tí o ba n ṣe àwọn nǹkan iruju pe o da gẹgẹ bii adaranjẹ ti n da ẹran rẹ jẹ ni tòsí ilẹ̀ kan ti ẹni tí ó ni i ti da aabo bo o, o sunmọ ki awọn ẹran rẹ jẹ ninu ilẹ̀ ti a da aabo bo yii torí wiwa wọn ni tòsí ibẹ, bẹ́ẹ̀ naa ni ẹni ti n ṣe nnkan ti ìríjú wa ninu ẹ, pẹ̀lú ìyẹn o ti n sunmọ nǹkan eewọ, o si sunmọ ki o ko sinu rẹ. Lẹyin rẹ ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé baaṣi ẹran kan n bẹ ninu ara (oun naa ni ọkàn), ara yoo maa dáa pẹ̀lú dídára rẹ, o si maa bajẹ pẹ̀lú bibajẹ rẹ.
Lati ọdọ Shaddaad ọmọ Aos- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo há nǹkan méjì lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe: “Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan, ti ẹ ba ti fẹ pa nǹkan ki ẹ pa a dáadáa, ti ẹ ba ti fẹ du nǹkan, ki ẹ du u dáadáa, ki ẹni kọọkan yin pọ́n ọ̀bẹ rẹ ki ó mú, ki o si tètè ko ìsinmi ba nǹkan ti o fẹ dú”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe daadaa ni ọranyan le wa lori nibi gbogbo nǹkan. Dáadáa ni: Ìpayà Ọlọhun ni gbogbo ìgbà, níbi ìjọsìn fun Un, ati ṣíṣe oore, ati ki èèyàn má ṣe àwọn ẹ̀dá ni suta, ninu ìyẹn naa ni ṣíṣe dáadáa nibi pípa ati didu. Ṣíṣe dáadáa nibi pipa nigba ti a ba fẹ gba ẹsan: Pẹ̀lú sisẹṣa ọna ti o rọrun ju ti o si yára ju lati gba ẹ̀mí ẹni ti a fẹ pa. Ṣíṣe dáadáa nibi dídú nígbà tí a ba n dú nǹkan: Pẹ̀lú ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn pẹlu pípọ́n irinṣẹ naa, ki a si ma pọ́n ọn ni iwájú nǹkan ti a fẹ du ti o si n wò ó, ki a si ma dú u ni ibi tí ẹran-ọ̀sìn mìíràn wa ti o n wò ó.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Saheed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”.
Daarukutniy ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dandan ni ki eeyan ti aburu dànù kuro lọ́dọ̀ ara ẹni ati kúrò lọ́dọ̀ ẹlòmíràn, iru inira yòówù ko ri ki o jẹ, ko ni ẹtọ fun ẹnikẹ́ni ki o fi suta kan ara rẹ tabi ẹlòmíràn láìsí iyatọ. Ko si ni ẹtọ fun un ki o fi oró yaró; tori pe a kìí mu inira kúrò pẹ̀lú ìnira ayafi ti a ba fẹ gba ẹsan láìní kọjá ààlà. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé àdéhùn ìyà ìpalára fun ẹni tí ba n ko ìpalára ba àwọn èèyàn, ati ìnira fun ẹni tí ba n ko ìnira ba àwọn èèyàn.
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Jibril ko yẹ ni ẹni tí n pààrà fun un ti o si n pa a láṣẹ láti ni akolekan aládùúgbò ti ilé rẹ sunmọ, Mùsùlùmí ni tabi Kèfèrí, mọlẹbi ni tabi ẹni tí kii ṣe mọ̀lẹ́bí, pẹlu ṣiṣọ iwọ̀ rẹ, ki eeyan ma si fi suta kan an, ki èèyàn si maa ṣe daadaa si i, ki èèyàn si maa ṣe suuru lori suta rẹ, titi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi lérò pe imisi maa sọ̀kalẹ̀ pé ki a maa fun un ninu dúkìá aládùúgbò rẹ ti o ba fi silẹ lẹ́yìn iku rẹ latara bi o ṣe bàbàrà iwọ̀ rẹ, ati bi Jibril ṣe n pààrà rẹ.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'hud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”
Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé àwọn nǹkan ti ṣíṣe wọn wa ninu ẹbọ, ninu wọn ni: Akọkọ: Ọfọ̀: Oun ni ọ̀rọ̀ ti àwọn ara àsìkò ki Isilaamu to de fi maa n ṣe ìwòsàn, ti o ni ẹbọ nínú. Ìkejì: Àsokọ́ra lati ara ìlẹ̀kẹ̀ ati nǹkan ti o jọ ọ: Eyi ti wọn maa n so kọ ọmọdé lọrun, ati awọn ẹran-ọ̀sìn, ati nǹkan ti o yatọ si i, lati ti ojukoju dànù. Ikẹta: Oogun ifẹran: Eyi ti wọn ṣe lati jẹ ki ọkọ ati ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí wa nínú ẹbọ; torí pé o wa ninu fifi nǹkan ṣe okùnfà, ti kii sii ṣe okùnfà ti o ba òfin mu ti o rinlẹ pẹ̀lú ẹ̀rí, kii sii ṣe okùnfà ti ìmọ̀lára ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí. Ṣùgbọ́n àwọn òkùnfà ti o ba ofin mu gẹ́gẹ́ bii kika Kuraani, tabi eyi ti o jẹ ti ìmọ̀lára gẹ́gẹ́ bii àwọn oògùn ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí, èyí ni ẹtọ pẹlu adisọkan pe okùnfà ni, ati pe àǹfààní ati ìnira wa lọ́wọ́ Ọlọhun.
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ki a ma maa bú àwọn òkú, ati pe eyi wa ninu awọn iwa buruku; torí pé wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa ninu iṣẹ rere tabi buruku, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ pé èébú yii ko lee dé ọdọ wọn, o kan maa kó sùtá ba àwọn alààyè ni.
Láti ọ̀dọ̀ Jundub ọmọ Abdullahi Al-Qasriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá ki irun asunbaa, onítọ̀hún ti wa nínú ààbò Ọlọhun, nítorí náà ẹ ṣọ́ra ki Ọlọhun ma baa bi yin leere nǹkan kan ninu ààbò Rẹ̀; torí ẹni ti Ọlọhun ba bi leere nǹkan kan nínú ààbò Rẹ̀, yoo gba ẹsan lara rẹ, yoo si da ojú rẹ bo ilẹ̀ ninu ina Jahannama”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba ki irun alufajari ti wa ninu iṣọ Ọlọhun ati ààbò Rẹ, yoo maa da aabo bo o, yoo si maa ṣẹ́gun fun un. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣọ wa lara kúrò nibi títú àdéhùn naa ati biba a jẹ́, yálà pẹlu gbigbe irun alufajari ju silẹ ni, tabi ìkọlù ẹni ti n ki i, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn ti ba ààbò yii jẹ́, o si ni ẹtọ si àdéhùn ìjìyà ti o le koko pẹ̀lú pe ki Ọlọhun bi i leere nípa ohun tí o ṣe àṣeètó nibẹ nibi ẹtọ Rẹ, ẹni tí Ọlọhun ba bi léèrè, yoo gba ẹsan lara rẹ, lẹ́yìn náà yoo da oju rẹ bo ilẹ̀ ninu iná.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe saara kii din dúkìá ku, bi ko ṣe pe o maa n ti àwọn nǹkan ti o le ba a jẹ́ danu, Ọlọhun si maa n fi oore ńlá rọ́pò fun ẹni tí n ṣe saara, o maa wa jẹ alekun ni kii ṣe adinku. Amojukuro pẹlu ikapa lati gba ẹsan kii le ẹni ti o ba ṣe e kun nǹkan kan ayafi ni agbara. Ẹnikan ko nii tẹrí ba tori ti Ọlọhun, ti kii ṣe ti ibẹru ẹnikẹ́ni, tabi ti ẹ̀tàn, tabi wiwa anfaani kan lọ́dọ̀ rẹ, àyàfi ki ẹsan rẹ o jẹ gíga ati iyì.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé èèyàn ti o pe julọ ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dáa, bíi títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ọ̀rọ̀ rere, ati ki èèyàn má fi sùtá kan ẹlòmíràn. Mumini ti o loore julọ ni àwọn ti wọn loore julọ fun awọn obinrin wọn, gẹgẹ bii ìyàwó rẹ, ati awọn ọmọbìnrin rẹ, ati awọn arábìnrin rẹ, ati awọn mọlẹbi rẹ lóbìnrin; torí pé àwọn ni wọn ni ẹtọ si iwa dáadáa ju ninu awọn èèyàn.