





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ, maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe ọ ni anfaani, ki o si tun wa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun, má si kagara, ati pe ti nkankan ba ṣẹlẹ si ọ, o ko wa gbọdọ sọ pe kani mo ṣe báyìí nkan báyìí báyìí ni ko ba jẹ, ṣugbọn sọ pe kọdarullāh wa maa sha'a fa‘al "akọsilẹ Ọlọhun ni, nkan ti O si fẹ ni O ṣe", tori pe (lao) "kani" o maa ṣina iṣẹ satani»
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pe dajudaju Mumini, daadaa ni gbogbo ẹ, ṣugbọn Mumuni ti o ni agbara ninu igbagbọ rẹ ati ipinnu rẹ ati dukia rẹ ati eyiti o yatọ si i ninu awọn ọna agbara ni oore ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọn-un-gbọn si tun nífẹ̀ẹ́ si i ju Mumini ti o jẹ ọlẹ lọ. Lẹyin naa ni o sọ asọtẹlẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fun Mumini pẹlu ṣiṣe awọn igbiyanju nibi nkan ti yio ṣe e ni anfaani ninu awọn alamọri aye ati ọjọ ìkẹyìn, pẹlu fifara ti Ọlọhun ti O mọ ti ọla Rẹ si tun ga, ati wiwa iranlọwọ pẹlu Rẹ, ati gbigbe ara le E. Lẹyin naa o tun kọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kuro nibi ikagara ati ojuriro ati imaa ṣe ọlẹ nibi ṣiṣe nkan ti o maa ṣe anfaani ni aye ati ọrun. Ti Mumuni ba gbiyanju nibi iṣẹ, ti o si tun ṣe awọn okunfa, lẹni ti o n wa ikunlọwọ Ọlọhun, ti o si tun wa oore lati ọdọ Ọlọhun, ko wa sí nkankan fun un lẹyin rẹ ayaafi ki o fa gbogbo alamọri rẹ le Ọlọhun lọwọ, ki o si tun lọ mọ pe dajudaju èyí tí Ọlọhun ba sẹsa ni oore. Nitori naa ti adanwo ba ṣẹlẹ si i lẹyin ìyẹn, ko gbọdọ sọ pe: Ka ni mo ṣe bayii, nkan bayii bayii ni ko ba jẹ"; Ati pe dajudaju gbolohun (kani) maa n ṣina iṣẹ satani" nibi titako kadara, ati kika abamọ lori nkan ti o ti bọ, ṣugbọn o maa sọ lẹni ti o jupa jusẹ silẹ ti o si tun yọnu pe: "Kọddarọ Allāhu, wa maa Sha'a fa‘ala“, Ati pe nkan ti o ṣẹlẹ yẹn wa ni ibamu si nkan ti Ọlọhun gba lero, ati pe Aṣeyiowu-U ni In, ko si si ẹni ti o le da akọsilẹ rẹ pada, ati pe ko si ẹni ti o le dá idajọ rẹ pada.
Lati ọdọ Abu Waaqid Al-Laythiy - ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba ti o jade lọ si Hunayn o rekọja nibi igi kan ti o jẹ ti awọn ọṣẹbọ ti wọn n pe e ni: Dhaatu anwaat ti wọn maa n fi awọn nkan ija wọn kọ ọ, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ṣe dhaatu anwaat fun wa gẹgẹ bi wọn ṣe ni dhaatu anwaat, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Mimọ fun Ọlọhun! Eleyii da gẹgẹ bi nkan ti awọn ijọ Musa sọ {ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan} [Al-'A‘roof: 138] mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin».
Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waOjiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade lọ sí Hunayn oun ni: Aaye kan ti o wa laarin Tọọif ati Makkah, ti awọn saabe kan si wa pẹlu rẹ awọn ti wọn ṣẹṣẹ wọ inu Isilaamu, Ni wọn ba rekọja nibi igi kan ti wọn n pe e ni: “Dhaatu anwaat”, iyẹn ni pe: èyí tí o ni awọn asokọ, awọn ọṣẹbọ maa n gbe e tobi ti wọn si maa n so awọn nkan ija wọn kọ ọ ati awọn nkan miran lati fi wa alubarika, Ni wọn ba tọrọ lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ki o ṣe igi kan bii rẹ fun wọn, ti wọn o maa so awọn nkan ija wọn kọ, lati fi wa alubarika; lẹni ti wọn n lero pe alamọri yii lẹtọọ, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe afọmọ ní ti kikọ gbolohun naa, ati ní ti gbigbe titobi fun Ọlọhun, ti o si sọ pe dajudaju gbolohun yii jọ gbolohun awọn ijọ Musa fun un: {ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan}, Nigba ti wọn ri awọn ti wọn n jọsin fun oriṣa ni wọn wa tọrọ pe ki awọn naa ni awọn oriṣa gẹgẹ bi awọn ọṣẹbọ naa ṣe ni awọn oriṣa, ati pe eleyii ni itẹle ilana wọn, Lẹyin naa ni o wa funni niroo - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe dajudaju ijọ yii a maa tẹle ilana awọn Juu ati Kristẹni, ti a si maa ṣe iṣe wọn, lẹni ti o fi n kilọ kuro nibi ìyẹn.
Lati ọdọ Ibn Abbas, ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”.
Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati AhmadArakunrin kan wa si ọdọ Anabi, o si ba a sọro nipa ọrọ ara rẹ, lẹ́yìn naa o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ ati ohunkohun ti o ba fẹ”, Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, bá tako ọrọ yii o si sọ fun un pe sise idapọ fifẹ ẹda pẹ̀lú fifẹ Ọlohun pẹlu lẹ́tà “waw” jẹ ìsẹbọ kekere si Ọlọhun, ko si lẹtọọ fun Musulumi lati sọ ọ, Lẹ́yìn náà, ó ṣamọ̀nà rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà pé: “Ohunkóhun tí Ọlọ́hun nìkan ṣoṣo ba fẹ́,” nítorí náà ó maa ya Ọlọ́hun sọ́tọ̀ nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sì nii so fifẹ ẹni kankan mọ ọn pẹlu èyíkéyìí ninu iran asopọ.
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti mi, mo si ti bo apoti iko-nnkan-si ti o jẹ temi pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan n bẹ nibẹ, nigba ti o wa ri i, o fa a ya ti oju rẹ si pọn, o wa sọ pe: "Irẹ 'Aaisha, Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun" 'Aaisha sọ pe: "A si ge e, a si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- ninu ile rẹ, lo ba ri ti wọn ti bo apoti iko nnkan si kekere ti wọn gbe ẹru sinu rẹ pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan abẹmi n bẹ nibẹ, awọ oju rẹ si yipada ni ti ibinu nitori Ọlọhun, o si fa a ya, o wa sọ pe: Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun pẹlu awọn aworan wọn. 'Aaisha sọ pe: A si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì.
Lati ọdọ Abu Hurairah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ọlọhun sọ pe: Ọmọ Adam pe Mi ni opurọ, ko si tọ fun un, o si bu mi, ko si tọ fun un, pipe ti o pe Mi ni opurọ ni ọrọ rẹ ti o sọ pe: Ko lee da mi pada gẹgẹ bi O ṣe da mi ni akọkọ, akọkọ ẹ̀dá ko si rọrùn fun mi ju dida a pada lọ, ṣùgbọ́n èébú tí ó bu Mi ni ọrọ rẹ ti o sọ pe: Ọlọhun ni ọmọ, Ọkan ṣi ni Mi, Ajironukan ni Mi, Mi o bímọ, wọn o si bi Mi, ko si si ẹni kan ti o jọ Mi".
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ninu haiisi kudsiy pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn sọ nípa àwọn ọṣẹbọ ati awọn Kèfèrí pe wọn n pe Oun ni opurọ, wọn si n ròyìn Rẹ pẹlu abuku, ìyẹn ko si tọ fun wọn. Nipa pipe E ni opurọ ni: ero wọn pe Ọlọhun ko lee da wọn pada lẹyin iku wọn gẹgẹ bi O ṣe da wọn ni akọkọ lati ibi àìsí, O wa fesi fun wọn pe Ẹni ti O bẹrẹ dida ẹ̀dá lati ibi àìsí ni ikapa lati da wọn pada, koda oun ni o rọrùn jù, bi o ti lẹ je pe bákan náà ni mejeeji ṣe ri ni ọdọ Ọlọhun ati dida ati dida pada, Ọlọhun ni ikapa lórí gbogbo nnkan. Ni ti eebu wọn: oun ni ọrọ wọn pe: O ni ọmọ, O wa fesi fun wọn pe Ọkan ni Oun, Oun si da ni gbogbo pipe nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn iṣe Rẹ, O mọ kuro nibi gbogbo àléébù, Ajironukan ni ti ko bukaata si ẹni kankan, ti gbogbo èèyàn si n bukaata si I, ko bi ọmọ kankan, ko si jẹ ọmọ fun ẹni kankan, ko si si ẹni ti o jọ Ọ, mimọ ni fun Un.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹni ti o ba mu aayo mi ni ọta, Mo ti kede ogun pẹlu rẹ, ati pe ẹru Mi o nii sunmọ Mi pẹlu nkankan ti Mo nífẹ̀ẹ́ si ju nkan ti Mo ṣe ni ọranyan fun un lọ, àti pe ẹru Mi ko nii yẹ ko nii gbo lẹni ti yio maa sunmọ Mi pẹlu awọn aṣegbọrẹ titi ti maa fi nífẹ̀ẹ́ rẹ, ti Mo ba ti wa nífẹ̀ẹ́ rẹ: Maa di igbọrọ rẹ ti yoo fi maa gbọrọ, maa di iriran rẹ ti yio fi maa riran, maa si di ọwọ rẹ ti yio fi maa mu nkan, Maa si tun di ẹsẹ rẹ ti yio fi maa rin, ti o ba wa bi Mi leere maa fun un, ti o ba si tun wa iṣọra pẹlu Mi maa sọ ọ, Mi o fa sẹyin nibi nkankan ti Mo fẹ ṣe bii ifasẹyin Mi nibi gbigba ẹmi mumini, ti o n korira iku ti Emi naa si n korira fifi ara ni in».
Bukhaariy gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo ninu hadīth qudusiy pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn sọ pe: Ẹni ti o ba fi suta kan aayo kan ninu awọn aayo Mi, ti o wa mu inu bi i, ti o tun korira rẹ, Mo ti fi mọ ọn Mo si ti kede ibasọta fun un. Ati pe aayo Ọlọhun ni: Mumini olupaya, ati pe lori odiwọn nkan ti n bẹ fun ẹru ni igbagbọ ati ipaya ni yio maa jẹ ipin rẹ nibi ijẹ aayo Ọlọhun. Ati pe musulumi o nii maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu nkankan ti yoo nífẹ̀ẹ́ si ju nnkan ti O ṣe ni ọranyan ti O si tun ṣe ni dandan lọ ninu ṣiṣe awọn nǹkan ti sharia pàṣẹ rẹ ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ, ati pe musulumi o nii yẹ ko nii gbo lẹni ti yio maa sunmọ Oluwa rẹ pẹlu awọn aṣegbọrẹ mọ awọn ọranyan; titi ti ọwọ rẹ o fi tẹ ifẹ Ọlọhun. Ti Ọlọhun ba ti wa nífẹ̀ẹ́ rẹ, Ọlọhun ni yio maa tọ́ ọ sọ́nà nibi awọn oríkèé ara mẹrẹẹrin yii: Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi igbọrọ rẹ, nitori naa ko nii gbọ́ nkankan ayaafi nkan ti yoo yọ Ọlọhun ninu. Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi iriran rẹ, nitori naa ko nii wo nkankan ayaafi nkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si wiwo o ti O si tun yọnu si i. Yoo tọ́ ọ sọ́nà nibi ọwọ rẹ, nítorí naa ko nii fi ọwọ rẹ ṣe nkankan ayaafi nkan ti yio yọ Ọlọhun ninu. Yoo tun tọ ọ sọ́nà nibi ẹsẹ rẹ, nitori naa ko nii maa rin ayaafi lọ sibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ninu, ko si nii maa ṣe igbiyanju ayaafi sibi nkan ti oore wa nibẹ. Pẹlu eyi, ti o ba bi Ọlọhun leere nkankan dajudaju Ọlọhun O fun un ni nkan ti o beere, nitori naa yio jẹ ẹni ti adua rẹ o maa gba, ti o ba si tun wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ti o tun sadi I lẹni ti n wa aabo, dajudaju Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un O ṣọ ọ, yoo si tun da aabo bo o nibi nkan ti o n paya. Lẹyin naa ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Mi o fa sẹyin nibi nkankan ti Mo fẹ ṣe bii ifasẹyin Mi nibi gbigba ẹmi Mumini ni ti ikaaanu rẹ; nítorí pé o korira iku latari inira ti o wa nibẹ, ati pe Ọlọhun si korira nkan ti yio maa ni mumini lara.
Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir Al-Juhaniy - ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ikọ kan wa ba a, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn ti o ka ọwọ duro fun ẹnikan, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan o si fi eleyii silẹ? O sọ pe: «Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ», ni o (arakunrin yẹn) wa ti ọwọ rẹ wolẹ ti o si fa a ja, nigba naa ni o (Anabi) wa gba ọwọ adehun (ibura) rẹ, ni o wa sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)».
Ahmad ni o gba a waAwọn ikọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti onka wọn sì jẹ mẹwaa, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn lori Isilaamu ati itẹle aṣẹ, ti ko si gba ọwọ adehun (ibura) ti ẹni kẹwàá, nigba ti wọn wa beere nipa idi ìyẹn o sọ - ki ikẹ ati ọla maa ba a - pe: Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ, oun naa ni nkan ti wọn maa n de tabi ti wọn maa n sokọ latara ilẹkẹ ati nkan miran yatọ si i lati fi ti ojukoju tabi inira danu. Ni arakunrin naa wa ti ọwọ rẹ bọ aaye ti agbekọ naa wa ti o si ja a ti o si bọra kuro nibẹ, nigba naa ni o gba ọwọ adehun pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o (Anabi) wa sọ lẹni ti n kilọ kuro nibi agbekọ ti o si n ṣe alaye idajọ rẹ pe: Ẹni ti o ba so agbekọ ó ti ṣe ẹbọ (mu orogun mọ Ọlọhun)”
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn ».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju awọn malaika o nii wa pẹlu ikọ arin irin-ajo kan ti aja n bẹ pẹlu wọn, tabi agogo ti wọn maa n gbe kọ ọrun awọn ẹranko ti wọn maa n gùn ti yio maa mu ohun wa ti o ba ti n lọ.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe dajudaju musulumi ti Isilaamu rẹ pe oun ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ, ko nii bu wọn, ko si nii ṣepe fun wọn, ko si nii sọ ọrọ wọn lẹyin, ko si nii maa fi ahọn rẹ tan èyíkéyìí ninu awọn iran ṣuta ka laarin wọn, Ti wọn si tun la ni ọwọ rẹ, ko si nii tayọ ẹnu-ala si wọn, ko si nii gba awọn dukia wọn ni ọna aitọ, ati nkan ti o jọ ìyẹn, Ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o gbe nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe leewọ jusilẹ.