





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Salamah ọmọ Al-hakwa'u- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa", nnkan ko kọdi rẹ afi igberaga, o sọ pe: Ko si lee gbe e si ẹnu rẹ mọ.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ri arakunrin kan ti o n jẹun pẹlu ọwọ rẹ osi, o wa pa a láṣẹ lati jẹun pẹlu ọwọ rẹ ọtun, Arakunrin naa wa da a lohun ni ti igberaga ati irọ pe oun ko ni ikapa! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹbi le e pe ki wọn ṣe jijẹ pẹlu ọwọ ọtun leewọ fun un, Ọlọhun ba gba adura Anabi Rẹ pe ki ọwọ ọtun rẹ rọ, ko si lee gbe e si ẹnu rẹ lẹyin ìyẹn pẹlu oúnjẹ tabi nǹkan mimu.
Lati ọdọ Abu Umaamah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣe khutubah ni hajj idagbere, o sọ pe: "Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín".
Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe khutubah ni ọjọ 'Arafah, ni hajj idagbere, ni ọdun kẹwàá ninu hijira, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dagbere fun awọn eniyan nibẹ, O pa awọn eniyan patapata láṣẹ lati bẹru Oluwa wọn pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn ẹ̀kọ̀ Rẹ. Pe ki wọn maa ki awọn irun maraarun-un ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe wọn ni ọran-anyan ni ọsan ati alẹ. Pe ki wọn maa gba awẹ oṣu Ramadan. Pe ki wọn maa yọ saka awọn dukia fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ki wọn si ma ṣe ahun pẹlu rẹ. Pe ki wọn maa tẹle awọn ti Ọlọhun fi ṣe adari le wọn lori, yàtọ̀ si ibi ṣiṣẹ Ọlọhun, Ẹni ti o ba ṣe awọn nnkan ti a dárúkọ yìí, ẹsan rẹ ni wiwọ alujanna.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?" Wọn sọ pe bẹẹni irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ṣíṣe aluwala ni pípé lori ìnira, ati gbigbe igbẹsẹ pupọ lọ si mọsalasi, ati rireti irun lẹyin irun, ìyẹn ni ida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi awọn saabe rẹ leere pe ṣe wọn fẹ ki oun tọka wọn si awọn iṣẹ ti o maa jẹ okunfa aforijin awọn ẹṣẹ, ati iparẹ rẹ kuro ninu awọn iwe awọn mọlaika ti wọn n kọ iṣẹ, ati gíga awọn ipò ninu alujanna? Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn. O sọ pe: Akọkọ: Kikari ati pipe aluwala lori inira; gẹgẹ bii otutu, ati kíkéré omi, ati inira ara, ati omi gbigbona. Ikeji: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbesẹ- oun ni nnkan ti o wa laaarin ẹsẹ mejeeji- lọ si awọn mọsalasi latara jijina ilé, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ pipaara. Ikẹta: Rireti asiko irun, ati sisopọ ọkan mọ ọn, ati ìgbáradì fun un, ati jijokoo sinu mọsalasi fun ireti janmọọn, ti o ba ti ki i ki o maa reti irun miiran ni aaye ti o ti kirun. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju awọn àlámọ̀rí yii gan-an ni dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú; nitori pe o maa n kọdi awọn oju ọna èṣù lọ sọ́dọ̀ ẹmi, o si maa n bori ifẹ inu, ti o maa kọ fun un kuro nibi gbigba awọn royiroyi wọle, ti ijọ Ọlọhun fi maa bori awọn ọmọ ogun èṣù pẹlu rẹ; ìyẹn ni ijagun soju ọna Ọlọhun ti o tobi julọ, o waa wa ni ipo dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú ọ̀tá.
Lati ọdọ Abu Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yín, ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Oluwa yin, ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipo yin ti o si loore julọ fun yin ju nina wura ati fadaka lọ, ti o si loore julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Wọn sọ pé: Bẹẹni. O sọ pe: "Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-".
Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- beere lọwọ awọn saabe rẹ pé: Njẹ ẹ fẹ ki n fun yin ni iro ki n si kọ yin ni eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yin ati eyi ti o niyi julọ ninu rẹ ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Ọlọhun Ọba Olukapa- Alagbara ti O gbọnngbọn-? Ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipò yin ninu alujanna? Ti o loore julọ fun yin ju ṣíṣe saara pẹlu wura ati fadaka lọ? Ati eyi ti o daa julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin fun ogun lọ, ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni gbogbo asiko ati lori gbogbo isẹsi.
Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo wa lori ijoko pẹlu Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nigbati awọn arakunrin meji nbu arawọn, ojú ọkan nínú àwọn mejeeji pọ́n kankan, bẹẹni iṣan parikẹ rẹ naa ntana jade, bayi ni Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) sọ pé: "Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ ni wọ́n bá sọ fún un pe: dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "yáa wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù" (Satani), Arakunrin náà bá dahun pe: Se weere kọlu mi ni bi?
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niArakunrin meji njà lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), bẹẹ ni oju ọkan ninu awọn mejeeji ti pọ́n koko, bẹẹ ni isan to yipo ọrun rẹ ti ran jáde. Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá sọ pé: Dajudaju emi mọ gbólóhùn kan ti ẹni to nbinu yii bá wí i, ibinu naa yóò sa kuro fun, ti o ba le sọ pé: mo sa di Ọlọhun nibi aburu èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe. Wọ́n sọ fun un pe: Dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: Wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani). Ni o ba dahun, o ni: se were ni mi bi?! o le ro pe ẹnikan kò nii wá isọra nipa èṣù (Satani) ayáafi ẹni tí o ba ya were.
Lati ọdọ Abu Qatada - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ pé: Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba se bẹẹ dájúdájú ala náà kòní kó ìnira ba a".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pé ala daada ti o dun ni ninu láti ojú orun lati ọdọ Ọlọhun ni ti nwa, bẹẹ ni alakala ti ko da ti o si nbani nínú jẹ, lati ọdọ èṣù ni ti nwa. Ẹni k'ẹni ti o bá lala ri nkan ti kò wu u, ki o ya tutọ sí apá òsì rẹ, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburu ala naa, ala náà ko nii ko aburú ba nitoripe Ọlọhun ti fi gbolohun ti o sọ yẹn se okunfa àkóyọ nibi nkan ti kò fẹ ti o le t'ara ala tí o la ṣẹlẹ.
Lati ọdọ 'Uqbatu ọmọ 'Aamir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: "Mo sọ pé: Mope irẹ ojisẹ Ọlọhun kini ìgbàlà? O sọ pé: “ko ahán rẹ ni ijanu, jẹ kí ilé rẹ gba ọ laaye, ki o si máa sunkún lori awọn àsise rẹ".
Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa'Uqbatu ọmọ 'Aamir ki Ọlọhun yọnu si beere lọwọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nipa Òkùnfà ti olugbàgbọ òdodo yóò fi ri àkóyọ láyé ati lọrun? Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Rẹ máa ba) wa sọ pé: nkan mẹta di ọwọ rẹ: Èkíní: ṣọ ahán rẹ kúrò níbi nkan ti kosi oore nibẹ, ati kúrò níbi gbogbo ọrọ aburu, ma se sọ ọrọ kan afi ko jẹ ọrọ daada. Ikeji: fìdí rẹ mọ ile rẹ ki o lè máa ṣe ìjọsìn fún Ọlọhun ni kọkọ (nigbati o ba da wa), gbaju mọ itẹle aṣẹ Ọlọhun Ọba to gbọngbọn ti o tun ga jùlọ, dáwà ninu ile rẹ lati sa fún wahala. Ikẹta: Máa sunkún ki o si máa ṣe àbámọ ki o si tuuba (tọrọ aforinjin ati iyọwọ kúrò) ni bi awọn ẹsẹ ti o ti ṣe kọja.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju larubawa oko kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan" O sọ pe: Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura mi ko nii lekun lori eyi, nigba ti o pa ẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹni ti o ba dun mọ ọn lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo eyi".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niArakunrin kan ninu awọn ara oko wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati tọ ọ sọ́nà lori iṣẹ ti o maa mu u wọ alujanna, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe dajudaju wiwọ alujanna ati lila kuro nibi ina, méjèèjì duro lori pipe awọn origun Isilaamu, bii ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ki o maa gbe irun maraarun-un ti Ọlọhun ṣe wọn ni dandan lori awọn ẹru Rẹ duro ni gbogbo ọsan ati oru. Ki o maa yọ saka owo ti Ọlọhun ṣe ni dandan lori rẹ, ki o si fun ẹni ti o lẹtọọ si i. Ki o maa ṣọ awẹ Ramadan ni asiko rẹ. Arakunrin naa sọ pe mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura pe mi ko nii lekun nnkan kan lori iṣẹ ti a ṣe ni ọran-anyan ti mo gbọ́ lọdọ rẹ ninu awọn itẹle, mi ko si nii dinkun ninu rẹ. Nigba ti o pẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba dun mọ ọn ninu lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo larubawa oko yii.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tọrọ iyẹpẹrẹ ati idojuti titi o fi da gẹgẹ bii pe o ki imu rẹ bọ inu erupẹ- o paara rẹ lẹẹmẹta- wọn wa bi i leere pé: Tani ẹni yii irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ti o ṣepe fún? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba awọn obi rẹ mejeeji nigba ogbo- ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji-, ti wọn ko wa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ; ìyẹn maa ri bẹẹ torí aiṣe daadaa si awọn mejeeji ati ṣiṣẹ awọn mejeeji.